ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 17 SÍ 23
Àṣẹ Máa Ń Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹni Tó Bá Ń Ṣi Agbára Lò
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ṣẹ́bínà ni ìríjú “tí ń ṣe àbójútó ilé,” Ọba Hesekáyà. Òun ni igbákejì ọba, ó sì ní ọ̀pọ̀ ojúṣe láti bójú tó.
- Ó yẹ kí Ṣẹ́bínà pèsè ohun táwọn èèyàn Jèhófà nílò 
- Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan ńláńlá ló ń wá fún ara rẹ̀ 
- Jèhófà fi Élíákímù rọ́pò Ṣẹ́bínà 
- Ọlọ́run sọ pé òun máa fún Élíákímù ní “kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì,” èyí to fi hàn pé Ọlọ́run máa gbé agbára àti àṣẹ wọ Élíákímù 
Rò ó wò ná: Báwo ni Ṣẹ́bínà ì bá ṣe lo ipò tó wà kó lè ran àwọn míì lọ́wọ́?