MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Jèhófà . . . Ìwọ Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé”
Ó ṣe pàtàkì pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lásìkò tó rọgbọ àti nígbà tí nǹkan bá nira. (Sm 25:1, 2) Ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù tó wà ní Júdà dojú kọ ìṣòro kan tó dán ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run wò. A rí ẹ̀kọ́ tó pọ̀ kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. (Ro 15:4) Lẹ́yìn tó o bá ti wo fídíò náà “Jèhófà . . . Ìwọ Ni Mo Gbẹ́kẹ̀ Lé,” gbìyànjú láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
- Ìṣòro wo ni Hesekáyà dojú kọ? 
- Báwo ni Hesekáyà ṣe fi ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Òwe 22:3 sílò nígbà tó kíyè sí i pé ó ṣeé ṣe káwọn Ásíríà sàga ti àwọn? 
- Kí nìdí tí Hesekáyà kò fi ronú pé káwọn juwọ́ sílẹ̀ fún Ásíríà tàbí kí òun wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Íjíbítì? 
- Báwo ni Hesekáyà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn Kristẹni? 
- Kí lóhun tó lè dán ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà wò lóde òní?