MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé O Máa Ń Dárí Ji Ara Rẹ?
Ó sábà máa ń ṣòro fún wa láti dárí ji ara wa, tá a bá ń rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn, tó sì jẹ́ pé Jèhófà ti dárí jì wá. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nínú àsọyé kan tó ní fídíò nínú nígbà Àpéjọ Àgbègbè “Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà!” tá a ṣe lọ́dún 2016. Wo fídíò náà lórí JW Library lẹ́ẹ̀kan sí i, kí o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
- Báwo ló ṣe pẹ́ tó kí wọ́n tó gba Ṣadé pa dà? 
- Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo ni àwọn alàgbà kà fún Ṣadé, báwo ló ṣe ràn án lọ́wọ́? 
- Báwo ni àwọn ará ìjọ ṣe ṣe sí Ṣadé nígbà tí wọ́n gbà á pa dà? 
- Àwọn èrò wo ni Ṣadé máa ń ní, báwo ni bàbá rẹ̀ ṣe ràn án lọ́wọ́?