MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Tẹ̀ Lé Ìṣísẹ̀ Kristi Pẹ́kípẹ́kí
Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé, ní pàtàkì tá a bá ń kojú àdánwò tàbí inúnibíni. (1Pe 2:21-23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n bú Jésù, síbẹ̀ kò gbẹ̀san nígbà tí wọ́n ṣàìdáa sí i. (Mk 15:29-32) Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á? Ó pinnu láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Jo 6:38) Ó tún pọkàn pọ̀ sórí “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀.”—Heb 12:2.
Tí wọ́n bá hùwà tí kò dáa sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́, kí ló yẹ ká ṣe? Kristẹni tòótọ́ kì í “fi ibi san ibi.” (Ro 12:14, 17) Tá a bá fara wé bí Kristi ṣe fara da ìnira, èyí á jẹ́ ká láyọ̀ torí pé inú Ọlọ́run dùn sí wa.—Mt 5:10-12; 1Pe 4:12-14.
WO FÍDÍÒ NÁÀ ORÚKỌ JÈHÓFÀ LÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- Báwo ni Arábìnrin Pötzingera ṣe fi ọgbọ́n lo àkókò rẹ̀ nígbà tí wọ́n fi í sínú yàrá àdágbé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n? 
- Ìyà wo ni Arákùnrin àti Arábìnrin Pötzinger fara dà nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tí wọ́n wà? 
- Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á? 
Tó o bá ń jìyà, máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi pẹ́kípẹ́kí
a Wọ́n tún lè pe orúkọ yìí ní Poetzinger.