MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà
Báwo lẹ́nì kan ṣe lè mú ẹ̀bùn dání wá fún Jèhófà lónìí? (1Kr 29:5, 9, 14) Tá a bá fẹ́ fí ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe bóyá fún ìjọ tàbí fún iṣẹ́ kárí ayé, oríṣiríṣi ọ̀nà tó wà nísàlẹ̀ yìí la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.
ỌRẸ TÁ A FI RÁNṢẸ́ LÓRÍ ÌKÀNNÌ TÀBÍ ÈYÍ TÁ A FI SÍNÚ ÀPÓTÍ:
- IṢẸ́ KÁRÍ AYÉ- a máa ń fi kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, a sì máa ń fi tún wọn ṣe - àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run - àwọn tó wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún - ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá - títẹ ìwé, fídíò àti àwọn ìtẹ̀jáde orí ìkànnì 
- ỌRẸ FÚN ÌNÁWÓ ÌJỌ- àwọn ìnáwó ìjọ, irú bí owó iná, owó omi àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba - àwọn ìpinnu tí ìjọ ti ṣe láti fi iye owó kan pàtó ránṣẹ́ sí ètò Ọlọ́run fún: - kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ kárí ayé 
- Ètò Ìrànwọ́ Kárí Ayé 
- àwọn iṣẹ́ kárí ayé míì 
 
ÀWỌN ÀPÉJỌ ÀYÍKÁ ÀTI ÀGBÈGBÈ
A máa ń fi àwọn ọrẹ tá a ṣe nígbà àpéjọ àgbègbè ránṣẹ́ fún iṣẹ́ kárí ayé. Inú ọrẹ kárí ayé la ti máa ń mú owó tá a ná lórí àpéjọ àgbègbè, àkànṣe àpéjọ àti àpéjọ àgbáyé.
Àwọn ọrẹ tá a ṣe nígbà àpéjọ àyíká la máa ń fi sanwó ibi tá a ti ń ṣe àpéjọ, a máa ń fi tún ibẹ̀ ṣe, a sì fi ń ṣe àwọn nǹkan míì tó bá yẹ. Àyíká kan sì lè pinnu láti fi owó tó bá ṣẹ́ kù ránṣẹ́ sí ètò Ọlọ́run fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé.