MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ni Kó O Máa Lé
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Olùkọ́ Atóbilọ́lá ni Jèhófà, ó ń fún wa ní ẹ̀kọ́ tó dáa jù lọ. Ó ń kọ́ wa bá a ṣe lè gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀, ó sì ń múra wa sílẹ̀ fún ọjọ́ iwájú aláyọ̀ tá à ń retí, gbogbo èyí ló ń ṣe fún wa lọ́fẹ̀ẹ́! (Ais 11:6-9; 30:20, 21; Ifi 22:17) Jèhófà tún ń lo ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yìí láti múra wa sílẹ̀ fún iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là tá à ń ṣe lónìí.—2Kọ 3:5.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
- Sapá láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníwà pẹ̀lẹ́.—Sm 25:8, 9 
- Máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ báyìí, irú bí iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ 
- Ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí.—Flp 3:13 
- Yááfì àwọn nǹkan, kó o bàa lè tóótun láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i.—Flp 3:8 
WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ̀KỌ́ JÈHÓFÀ SỌ WÁ DI ỌLỌ́RỌ̀ NÍPA TẸ̀MÍ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- Irú àwọn ìṣòro wo ni àwọn akéde kan ti borí kí wọ́n lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run? 
- Irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni àwọn tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run máa ń rí gbà? 
- Nígbà tí àwọn tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí dé ibi iṣẹ́ àyànfúnni wọn, báwo ni àwọn ará ìjọ ibẹ̀ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́? 
- Kí ni ẹni tó bá fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ dójú ìlà ẹ̀? (kr 189) 
- Èwo nínú àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ míì tí ètò Ọlọ́run pèsè lo tún lè fi ṣe àfojúsùn rẹ? 
Àwọn ìbùkún wo lo máa rí tó o bá fi ṣe àfojúsùn rẹ láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run?