MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kí Ni Jèhófà Máa Fẹ́ Kí N Ṣe?
Ká tó ṣe ìpinnu, ó kéré ni, ó pọ̀ ni, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Kí ni Jèhófà máa fẹ́ kí n ṣe?’ Lóòótọ́ kò sí báa ṣe lè mọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn Jèhófà, àmọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ti jẹ́ ká mọ gbogbo ohun tá a nílò ká lè gbára dì fún “gbogbo iṣẹ́ rere.” (2Ti 3:16, 17; Ro 11:33, 34) Jésù fòye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́, ó sì fi ìfẹ́ Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ̀. (Jo 4:34) Bíi ti Jésù, àwa náà lè ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn.—Jo 8: 28, 29; Ef 5:15-17.
WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ MÁA FI ÒYE MỌ OHUN TÍ ÌFẸ́ JÈHÓFÀ JẸ́ (LE 19:18), KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé wa? 
- Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan orin tá a máa gbọ́? 
- Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan aṣọ tá a máa wọ̀ àti ìmúra wa? 
- Àwọn apá wo ní ìgbésí ayé wa ló tún yẹ ká ti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò? 
- Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe? 
Kí ni àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe ń sọ nípa àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà?