MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé O Lè Lo Àkókò àti Okun Rẹ?
Bí wòlíì Àìsáyà ṣe sọ, à ń rí bí ètò Jèhófà tó wà láyé ṣe ń tẹ̀ síwájú, tó sì ń gbòòrò sí i. (Ais 54:2) Torí náà, a túbọ̀ máa nílò àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì. Tá a bá sì ti kọ́ wọn tán, ó dájú pé a máa ní láti máa bójú tó wọn, àwọn míì sì lè nílò àtúnṣe. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà lo àkókò àti okun rẹ fún Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ yìí?
- O lè rí i pé ìwọ náà wà níbẹ̀ tí wọ́n bá ní kẹ́ ẹ wá tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe 
- O lè yọ̀ǹda ara rẹ láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n ṣe ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe 
- O lè kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Local Design/Construction Volunteer Application (DC-50) kó o lè máa yọ̀ǹda ara rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan fún iṣẹ́ ìkọ́lé tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn àtúnṣe kan nítòsí ibi tó ò ń gbé 
- O lè kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Application for Volunteer Program (A-19) kó o lè yọ̀ǹda ara rẹ fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní agbègbè rẹ̀ tàbí ní ilé míì tá a yà sí mímọ́ fún ìjọsìn Jèhófà 
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ À Ń MÚRA SÍLẸ̀ LÁTI KỌ́ ILÉ TUNTUN—ÀYỌLÒ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- Látọdún 2014, báwo la ṣe túbọ̀ ń lo fídíò? 
- Ká lè túbọ̀ máa ṣe ọ̀pọ̀ fídíò jáde, kí làwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe, ìgbà wo la fẹ́ bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo la sì fẹ́ parí ẹ̀? 
- Báwo la ṣe lè ti iṣẹ́ yìí lẹ́yìn? 
- Tó bá wù ẹ́ láti yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìkọ́lé ní Ramapo, kí nìdí tó fi yẹ kó o kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù (DC-50) kó o sì yọ̀ǹda ara rẹ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n bá ń ṣe ládùúgbò rẹ? 
- Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà ló ń darí iṣẹ́ yìí? 
- Kí la lè ṣe láti ṣèrànwọ́ tá ò bá tiẹ̀ lè lọ síbi ìkọ́lé yìí?