MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bópẹ́bóyá, Kò Sí Ìṣòro Tí Ò Ní Dópin
Ìṣòro máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni, pàápàá tó bá jẹ́ ìṣòro tí ò lọ bọ̀rọ̀. Dáfídì mọ̀ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tóun máa bọ́ lọ́wọ́ Ọba Sọ́ọ̀lù, òun sì máa di ọba bí Jèhófà ṣe ṣèlèrí fún òun. (1Sa 16:13) Ìgbàgbọ́ tí Dáfídì ní yìí ló mú kó ní sùúrù, kó sì dúró de Jèhófà.
Tá a bá níṣòro, a sábà máa ń ronú nípa ọgbọ́n tá a lè dá tàbí ohun tá a lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà. (1Sa 21:12-14; Owe 1:4) Bó ti wù kó rí, àwọn ìṣòro kan kì í lọ láìka bá a ṣe sapá tó láti fi ìlànà Bíbélì yanjú wọn. Nírú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní sùúrù dìgbà tí Jèhófà máa dá sí ọ̀rọ̀ náà. Láìpẹ́, Jèhófà máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá, á sì “nu gbogbo omijé” kúrò ní ojú wa. (Ifi 21:4) Yálà Jèhófà ló yanjú ìṣòro wa tàbí nǹkan míì ló ṣẹlẹ̀ tó mú kí ìṣòro náà lọ, ohun kan dájú: Bópẹ́bóyá, kò sí ìṣòro tí ò ní dópin. Ìrètí yìí lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ tá a bá níṣòro.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN ÈÈYÀN TÓ WÀ NÍṢỌ̀KAN NÍNÚ AYÉ TÓ PÍN YẸ́LẸYẸ̀LẸ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
- Ìṣòro wo làwọn ará wa ní gúúsù orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dojú kọ? 
- Kí ni wọ́n ṣe tó fi hàn pé wọ́n ní sùúrù, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn? 
- Kí ni wọ́n ṣe tó fi hàn pé “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” ni wọ́n gbájú mọ́?—Flp 1:10