INDONÉṢÍÀ
Ọ̀gá Àwọn Jàǹdùkú Di Ọmọlúwàbí
Hisar Sormin
- WỌ́N BÍ I NÍ 1911 
- Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1952 
- ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọ̀gá àwọn jàǹdùkú tó di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. 
LỌ́JỌ́ kan, Ọ̀gá Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ pe Arákùnrin Sormin pé kó wá rí òun ní ọ́fíìsì adájọ́ àgbà ti orílẹ̀-èdè náà.
Ọ̀gá náà sọ pé: “Ọmọ ilẹ̀ Indonéṣíà ni ẹ́, àbí? Sòótọ́ fún mi, kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà gan-an?”
Arákùnrin Sormin dáhùn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ara mi fún un yín. Ṣé ẹ rí i, ọ̀gá àwọn jàǹdùkú ni mí tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, mò ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe níbí nìyẹn, wọ́n ń sọ àwọn èèyànkéèyàn bíi tèmi di ọmọlúwàbí.”
Ọ̀gá Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ yìí wá kéde pe: “Àìmọye ẹ̀sùn láwọn èèyàn máa fi ń kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé ẹ̀sìn tòótọ́ lẹ̀sìn yìí nítorí ó jẹ́ kí Ọ̀gbẹ́ni Sormin yí pa dà.”