ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 189
  • Ṣé Mo Lè Rí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Máa Tù Mí Nínú Nínú Bíbélì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Mo Lè Rí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Máa Tù Mí Nínú Nínú Bíbélì?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ìṣòro tó lágbára
  • Ikú ẹni tó o nífẹ̀ẹ́
  • Kéèyàn máa dára ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ
  • Ìbànújẹ́
  • Àìsàn
  • Ìdààmú ọkàn
  • Ogun
  • Àníyàn nípa ọjọ́ iwájú
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Ọkùnrin Tó Ń Ṣàníyàn Lọ́wọ́?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Mò Ń Dá Ara Mi Lẹ́bi​—Ṣé Bíbélì Lè Mú Kára Tù Mí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kó Gbogbo Àníyàn Rẹ lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 189
Ara tu obìnrin kan bó ṣe ń ka Bíbélì.

Ṣé Mo Lè Rí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Máa Tù Mí Nínú Nínú Bíbélì?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bẹ́ẹ̀ ni. (Róòmù 15:4) Ẹ jẹ́ ká wo díè lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ti tu ọ̀pọ̀ nínú lásìkò tí wọ́n ní ìṣòro tó ń kó wọ́n lọ́kàn sókè.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa

  • Ìṣòro tó lágbára

  • Ikú ẹni tó o nífẹ̀ẹ́

  • Kéèyàn máa dára ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ

  • Ìbànújẹ́

  • Àìsàn

  • Ìdààmú ọkàn

  • Ogun

  • Àníyàn nípa ọjọ́ iwájú

Ìṣòro tó lágbára

Sáàmù 23:4: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri, mi ò bẹ̀rù ewukéwu, nítorí o wà pẹ̀lú mi.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tó o bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, tó o sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, wàá nígboyà láti kojú àwọn ìṣòro tó bá yọjú.

Fílípì 4:13: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run lè fún ẹ lókun láti fara da ìṣòro èyíkéyìí tó o bá dojú kọ.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ọlọ́jọ́ pípẹ́, ka àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro: Ìṣòro Tó Kọjá Agbára Wa.”

Ikú ẹni tó o nífẹ̀ẹ́

Oníwàásù 9:10: “Kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú, ibi tí ìwọ ń lọ.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn tó ti kú ò jẹ̀rora, wọn ò sì lè pa wá lára torí pé wọn ò mọ nǹkan kan mọ́.

Ìṣe 24:15: “Àjíǹde . . . yóò wà.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run lè jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe lè tù ẹ́ nínú tí ẹni tó o nífẹ̀ẹ́ bá kú, ka àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tó Lè Ran Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Lọ́wọ́.”

Kéèyàn máa dára ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ

Sáàmù 86:5: “Nítorí pé ẹni rere ni ọ́, Jèhófà,a o sì ṣe tán láti dárí jini; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tí wọ́n sì pinnu pé àwọn ò ní ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

Sáàmù 103:12: “Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tí Ọlọ́run bá ti dárí jì wá, kì í rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́. Kì í sì í fi àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn jẹ wá níyà.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe lè tù ẹ́ nínú tó o bá ń dára ẹ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, ka àpilẹ̀kọ náà “Mò Ń Dá Ara Mi Lẹ́bi​—Ṣé Bíbélì Lè Mú Kára Tù Mí?”

Ìbànújẹ́

Sáàmù 31:7: “O ti rí ìpọ́njú mi; o mọ ìdààmú ńlá tó bá mi.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run mọ gbogbo ohun tó ò ń bá yí. Ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ báwọn míì ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n.

Sáàmù 34:18: “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa dúró tiẹ̀ lásìkò tí inú ẹ ò bá dùn. Ó lè fún ẹ lókun láti fara da ìnira.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe lè mú kára tù ẹ́ tí inú ẹ ò bá dùn, wo fídíò náà O Lè Pa Dà Ní Ayọ̀.

Àìsàn

Sáàmù 41:3: “Jèhófà yóò fún un lókun lórí ibùsùn àìsàn rẹ̀.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run lè fún ẹ lókun kó o lè fara da àìsàn tó lágbára, á sì tún fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. Bákan náà, ó lè fún ẹ ní ọgbọ́n tó o nílò kó o lè ṣèpinnu tó tọ́.

Àìsáyà 33:24: “Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.’”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ṣèlérí pé láìpé gbogbo èèyàn máa gbádùn ìlera tó jí pépé.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da àìsàn, ka àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àìsàn Bá Dé Láìròtẹ́lẹ̀.”

Ìdààmú ọkàn

Sáàmù 94:19: “Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá yíjú sí Ọlọ́run nígbà tá a bá ní ìdààmú ọkàn, ó máa fi wá lọ́kàn balẹ̀.

1 Pétérù 5:7: “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ó máa ń dun Ọlọ́run tó bá rí i tá à ń jìyà. Ó sì rọ̀ wá pé ká gbàdúrà sí òun nípa àwọn ìṣòro wa.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe lè tù ẹ́ nínú tó o bá ní ìdààmú ọkàn, ka àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn.”

Ogun

Sáàmù 46:9: “Ó ń fòpin sí ogun kárí ayé.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ogun táwọn èèyàn ń jà.

Sáàmù 37:11, 29: “Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. . . . Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Àwọn olódodo máa gbádùn àlááfíà títí láé lórí ilẹ̀ ayé.

Tó o bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bá a ṣe mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?”

Àníyàn nípa ọjọ́ iwájú

Jeremáyà 29:11: “‘Mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.’”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run fi dá àwọn èèyàn ẹ̀ lójú pé kí wọ́n fọkàn balẹ̀ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

Ìfihàn 21:4: “Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run ṣèlérí pé láìpẹ́ àwọn ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí máa di ohun àtijọ́.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa.”

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́