ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwhf àpilẹ̀kọ 17
  • Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìròyìn Tó Ń Jáni Láyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìròyìn Tó Ń Jáni Láyà
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa wo ni ìròyìn máa ń ní lórí àwọn ọmọdé?
  • Kí lo lè ṣe táwọn ọmọ rẹ ò fi ní máa jáyà tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn?
  • “Àwa Nìyí! Rán Wa!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kejì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
ijwhf àpilẹ̀kọ 17
Ìdílé kan ń wo tẹlifíṣọ̀n. Bàbá rí í pé ìròyìn tó ń jáni láyà ń ba ọmọ òun lẹ́rù.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìròyìn Tó Ń Jáni Láyà

Kò sí ìgbà tí a kì í gbọ́ ìròyìn tó ń jáni láyà lórí tẹlifíṣọ̀n, lórí fóònù, nínú àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àti lórí kọ̀ǹpútà. Wọ́n sábà máa ń gbé fídíò ohun tó ń ṣẹlẹ̀ jáde nínú àwọn ìròyìn náà.

Gbogbo ẹ̀ sì làwọn ọmọ ń wò.

Kí lo lè ṣe tí ìròyìn tó ń jáni láyà ò fi ní máa dẹ́rù ba àwọn ọmọ rẹ?

  • Ipa wo ni ìròyìn máa ń ní lórí àwọn ọmọdé?

  • Kí lo lè ṣe tí àwọn ọmọ rẹ ò fi ní máa jáyà tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn?

  • Bí ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú bá ti ṣẹlẹ̀ lójú ọmọ rẹ̀ rí ńkọ́?

Ipa wo ni ìròyìn máa ń ní lórí àwọn ọmọdé?

  • Ìṣẹ̀lẹ̀ búburú táwọn ọmọdé ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n bá ń gbọ́ ìròyìn máa ń já wọn láyà. Àwọn ọmọdé kan lè má sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn o, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn pé ohun búburú kan ṣẹlẹ̀, àyà wọn máa ń já gan-an ni.a Tí wọ́n bá wá rí i pé ọkàn àwọn òbí àwọn ò balẹ̀ nítorí ìròyìn náà, ṣe ni ìbẹ̀rù tiwọn náà á tún pọ̀ sí i.

  • Àwọn ọmọdé lè ṣi ìròyìn tí wọ́n gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n lóye. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan sọ pé ohun táwọn rí yẹn á ṣẹlẹ̀ sí ìdílé àwọn. Àwọn ọmọdé tó bá sì ń wo fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan tó wáyé lọ́pọ̀ ìgbà lè rò pé ṣe ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń wáyé léraléra.

  • Àwọn ọmọdé ò ní mọ̀ bóyá àwọn oníròyìn tí ṣe àbùmọ́ ohun tó ṣelẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Wọ́n lè má mọ̀ pé ohun tó ń mówó wọlé fáwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ni pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ń sọ. Torí náà, wọn lè ṣe àbùmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ kó lè wu àwọn tó ń tẹ́tí sí wọn láti máa gbọ́ ìròyìn náà lọ.

Kí lo lè ṣe táwọn ọmọ rẹ ò fi ní máa jáyà tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn?

  • Má ṣe jẹ́ kí wọ́n máa tẹ́tí sí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tí ìròyìn bá gbé jáde. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé káwọn ọmọ rẹ má mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé o. Ṣùgbọ́n kò dára kí wọ́n máa tẹ́tí sí ìròyìn tó ń jáni láyà léraléra, yálà lórí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n.

    “Nígbà míì, èmi àti ọkọ mi máa ń sọ̀rọ̀ gan-an nípa ohun tá a gbọ́ nínú ìròyìn, láì kíyè sí i pé ó ń dẹ́rù ba àwọn ọmọ wa bó ṣe ń ta sí wọn létí.”—Maria.

    Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan.”​—⁠Òwe 12:​25, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

  • Fara balẹ̀ gbọ́ wọn, rọra fèsì. Tí ọmọ rẹ ò bá lè ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀, sọ pé kó yà á sórí ìwé. Tó o bá ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, èdè tó máa yé e ni kó o lò, ṣùgbọ́n má ṣe bá a sọ ohun tí kò yẹ kó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

    “Ó jọ pé tá a bá jókòó tá a sì gbọ́ ohun tí ọmọ wa fẹ́ sọ ni ara rẹ̀ máa ń balẹ̀. Ẹ̀rù á ṣì máa bà á tá a bá wulẹ̀ sọ pé, ‘Kò sí ohun tá a lè ṣe nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà báyìí, àfi ká yáa máa bá a yí.’”—Sarahi.

    Ìlànà Bíbélì: ‘Yára láti gbọ́rọ̀, lọ́ra láti sọ̀rọ̀.’​—Jémíìsì 1:⁠19.

  • Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí ìròyìn má bàa máa kó o láyà sókè. Ká sọ pé wọ́n jí ọmọ kan gbé, bí wọ́n ṣe sọ ọ́ nínú ìròyìn lè mú kò dà bíi pé àwọn gbọ́mọgbọ́mọ ti kún ìgboro, tí ọ̀rọ̀ ò sì rí bẹ́ẹ̀. Ṣàlàyé ohun tó o ti ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ fún wọn. Kó o sì tún fi sọ́kàn pé kì í ṣe torí pé ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan wọ́pọ̀ ni wọ́n ṣe gbé e jáde lórí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n, ìdí tí wọ́n fi gbé e jáde ni pé irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n.

    “Má ṣe dá àwọn ọmọ rẹ dá bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun téèyàn ń rò ló ń pinnu bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹni, torí náà, tá a bá ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tó dára, wọn ò ní bẹ̀rù mọ́.”​—Lourdes.

    Ìlànà Bíbélì: “Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń fún ẹnu rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye ó sì ń fi ìyíniléròpadà kún ọ̀rọ̀ rẹ̀.”​—Òwe 16:23.

a Ìbẹ̀rù máa ń mú káwọn ọmọdé tọ̀ sára nígbà tí wọ́n ń sùn tàbí kí ẹ̀rù máa bà wọ́n láti lọ síléèwé níbi tí ojú àwọn òbí wọn ò ti ní tó wọn.

Bí ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú bá ti ṣẹlẹ̀ lójú ọmọ rẹ̀ rí ńkọ́?

Ní May 7, 2019, àwọn ọ̀dọ́mọdé méjì kan bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn nílé ìwé kan ní Highlands Ranch, ní ìpínlẹ̀ Colorado, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n pa akẹ́kọ̀ọ́ kan, wọ́n sì ṣe ẹni mẹ́jọ léṣe. Ilé ìwé yẹn ni Jack, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ń lọ, ó sì wà níbẹ̀ lọ́jọ́ táwọn ọ̀dọ́mọdé yẹn wá yìnbọn. Àwọn òbí rẹ̀, Ben àti Casey, ṣàlàyé bí wọ́n ṣe sapá láti ran Jack lọ́wọ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ben àti Casey.

Ipa wo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ni lórí ọmọ yín?

Casey: Ṣe ni Jack máa ń wò fẹ̀tòfẹ̀tò fún ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ben: Ó lè ti máa ṣeré ẹ̀ jẹ́jẹ́ láìbẹ̀rù ohunkóhun, àmọ́ kó kan ṣàdédé sá wá bá wa bí ohun kan bá rán an létí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó máa ń ṣe Jack bíi pé gbogbo ìgbà ni ohun tí kò dára á máa ṣẹlẹ̀, a sì mọ̀ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yẹn ló mú kó máa rò bẹ́ẹ̀.

Ṣé ẹ wo báwọn ọmọ yẹn ṣe yìnbọn nínú ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n?

Casey: A kọ́kọ́ wò ó. Kódà, fún bí ọ̀sẹ̀ kan ni àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi ń wò ó lórí tẹlifíṣọ̀n. Lẹ́yìn náà ni ọkọ mi wá kíyè sí i pé bá a ṣe ń wò ó yẹn ń mú kí Jack máa ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀, ìyẹn sì ń mú kí àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta máa ṣàníyàn dípò ká máa ronú lórí ohun tá a lè ṣe tá ó fi mú un kúrò lọ́kàn.

Kí ni ohun tẹ́ ẹ rò pé ó ran Jack lọ́wọ́ jù lọ?

Casey: Eré ìmárale dín ìbẹ̀rù Jack kù, torí náà a máa ń wáyè láti ṣeé lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ká tẹ́tí sí Jack tó bá ní ohunkóhun bá wa sọ. Mo kíyè sí i pé nígbà tí gbogbo nǹkan bá ti pa lọ́lọ́, kó tó di pé Jack lọ sùn, ó máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún wa. Ìgbà míì wà tá a máa ń sọ̀rọ̀ fún wákàtí kan, ṣùgbọ́n ó máa ń rí ìrànlọ́wọ́ tó fẹ́ gbà. Jack mọ̀ pé kò yẹ kóun dá ọ̀rọ̀ náà dá ara òun, torí pé ó lẹ́ni tó lè fọ̀rọ̀ lọ̀.

Ìmọ̀ràn wo lẹ máa fún àwọn òbí tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú ti ṣẹlẹ̀ lójú ọmọ wọn rí?

Ben: Ó ṣe pàtàkì pé kí ọkàn àwọn ọmọ balẹ̀ nínú ilé kó tó di pé ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú wáyé. Bí ìṣẹ̀lẹ̀ tó búrú bá wá wáyé, ó máa rọrùn fún yín láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

Casey: Ọmọ ò ṣe é fi wéra. Ẹ̀rù lè tètè máa bá ọ̀kan ju òmíràn lọ. Àwọn kan tiẹ̀ lè rò pé ẹ ti ń dáàbò bo àwọn ọmọ yín jù, ẹ ṣáà rí i pé ohun tí ọmọ kọ̀ọ̀kan bá fẹ́ lẹ̀ ń ṣe fún un. Bí ìta bá tiẹ̀ ń lé àwọn ọmọ sá, ẹ túbọ̀ ṣe ara yín lọ́kan nínú ìdílé kí ọkàn àwọn ọmọ yín lè máa balẹ̀ tí wọ́n bá wà nílé.

Àtúnyẹ̀wò: Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti kojú ìròyìn tó ń jáni láyà?

  • Má ṣe jẹ́ kí wọ́n máa tẹ́tí sí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tí ìròyìn bá gbé jáde.

  • Fara balẹ̀ gbọ́ wọn, rọra fèsì.

  • Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí ìròyìn má bàa máa kó wọn láyà sókè.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́