ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwhf àpilẹ̀kọ 22
  • Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Moore

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Moore
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí òbí ṣe lè kọ́ ọmọ láti máa moore
  • “Ẹ Máa Dúpẹ́ Ohun Gbogbo”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ẹ̀mí Ìmoore
    Jí!—2016
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dúpẹ́ Oore?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Máa Dúpẹ́ Oore
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
Àwọn Míì
Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
ijwhf àpilẹ̀kọ 22
Ọmọbìnrin kan tó ń rẹ́rìn-ín tó sì na ìwé tó fọwọ́ ya ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ sí sókè.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Moore

Ìwádìí fi hàn pé àwọn èèyàn tó bá ń moore máa ń láyọ̀, wọ́n máa ń ní ìlera tó dáa, ó máa ń rọrùn fún wọn láti kojú ìṣòro, wọ́n sì máa ń ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Robert A. Emmons sọ pé ẹni tó bá moore “kì í ṣe ìlara, kì í ìbínú, kì í lójú kòkòrò àti kì í sì dììyàn sínú.”a

Bí àwọn ọmọ bá lẹ́mìí ìmoore, báwo lo ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní? Ìwádìí kan tí wọ́n fi ọdún mẹ́rin ṣe nípa àwọn ọ̀dọ́ tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje (700) fi hàn pé àwọn tó moore lára àwọn ọ̀dọ́ náà ò fi bẹ́ẹ̀ jíwèé wò nígbà ìdánwò, wọn ò mutí, wọn ò lo oògùn olóró, wọn ò sì hùwà tí kò tọ́.

  • Ẹní bá ń rò pé òun lẹ́tọ̀ọ́ sí gbogbo nǹkan kì í moore. Ọ̀pọ̀ ọmọdé máa ń rò pé ẹ̀tọ́ àwọn ni gbogbo ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn. Ẹni bá ń ronú pé ṣe làwọn tó ń ṣe òun lóore jẹ òun ní gbèsè irú oore bẹ́ẹ̀, máa ń ya abaramóorejẹ.

    Irú èrò bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ lóde òní. Ìyá kan tó ń jẹ́ Katherine sọ pé: “Ohun tí ayé yìí fi ń kọ́ni ni pé gbogbo nǹkan lèèyàn lẹ́tọ̀ọ́ sí. Ìwé ìròyìn, tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ń fi ọ̀pọ̀ nǹkan tó yẹ ká gbà pé a lẹ́tọ̀ọ́ sì hàn wá, ó sì ń sọ fún wa pé àwa ló yẹ ká kọ́kọ́ ní wọn.”

  • Ọmọdé lè kọ́ béèyàn ṣe ń moore láti kékeré. Ìyá kan tó ń jẹ́ Kaye sọ pé: “Àwọn ọmọdé dùn ún kọ́. Wọ́n kúkú sọ pé àtikékeré la ti ń pẹ̀ka ìrókò, torí náà àtikékeré ló yẹ ká ti fi ìwà rere kọ́ wọn àwọn ọmọdé.”

Bí òbí ṣe lè kọ́ ọmọ láti máa moore

  • Kọ́ wọn ni ohun tí wọ́n á sọ. Àwọn ọmọdé pàápàá lè kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ káwọn máa dúpẹ́ bí ẹnì kan bá fún wọn lẹ́bùn tàbí tó ṣe wọ́n lóore. Bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà tí wọ́n sì ń gbọ́n sí i, wọ́n á túbọ̀ máa mọrírì ohun táwọn míì bá ṣe fún wọn.

    Ìyá kan tó fa ọmọ rẹ̀ obìnrin dání bí ọmọ náà ṣe ń gba ẹ̀bùn bèbí tí wọ́n fi aṣọ ṣe. Àwọn méjèèjì ń rẹ́rìn-ín torí wọ́n mọrírì ẹ̀bùn náà.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa dúpẹ́.”—Kólósè 3:15.

    “Ọmọ-ọmọ wa tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta máa ń tètè sọ pé ‘ẹ ṣeun,’ tó bá sì fẹ́ béèrè fún nǹkan á kọ́kọ́ sọ pé ‘ẹ jọ̀wọ́.’ Ohun táwọn òbí rẹ̀ fi kọ́ ọ nìyẹn. Ìwà tí wọ́n ń hù àti bó ṣe gbọ́ tí wọ́n máa ń dúpẹ́ ló sọ òun náà di ẹni tó mọpẹ́ẹ́dá.”—Jeffrey.

  • Kọ́ wọn ní òun tí wọ́n á ṣe. O ò ṣe ní káwọn ọmọ rẹ kọ̀wé ìdúpẹ́ nígbà míì tí ẹnì kan bá fún wọn ní ẹ̀bùn kan? Tó o bá tún ń fún àwọn ọmọ rẹ̀ níṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ṣe nínú ilé, wàá jẹ́ kí wọ́n mọrírì bó ṣe gba ìsapá tó láti mú kí nǹkan máa lọ geerege nínú ìdílé.

    Àwọn òbí tó ń kọ́ àwọn ọmọ wọn bí wọ́n á ṣe kọ̀wé ìdúpẹ́.

    Ìlànà Bíbélì: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

    “Àwọn ọmọ wa méjèèjì tí ò tíì pé ogún ọdún máa ń ṣe ipa tiwọn nínú ilé. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń se oúnjẹ, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́ẹ̀ẹ̀pẹ́. Ìyẹn jẹ́ kí wọ́n mọrírì ìsapá àwa òbí wọn, wọ́n sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa.”—Beverly.

  • Kọ́ wọn ní ìwà tí wọ́n á hù. Bí ilẹ̀ tó dáa ṣe máa ń mú kí irúgbìn hù dáadáa, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe máa ń mú kéèyàn mọpẹ́ẹ́dá. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ máa ń gbà pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ ẹlòmíì káwọn tó lè ṣe ohunkóhun láṣeyọrí, ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó bá ràn wọ́n lọ́wọ́.

    Bàbá tó ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì bí wọ́n ṣe lè tún kẹ̀kẹ́ ṣe.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ, bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”—Fílípì 2:3, 4.

    “Nígbà míì tá a bá ń jẹ́un, a máa ń ṣeré tó ń rán wa létí pé ká máa dúpẹ́. Olúkúlùkù wa máa ń sọ ohun tó dúpẹ́ fún. Eré náà máa ń jẹ́ kí gbogbo wa ní èrò tó dáa, èrò tó fẹ́mì ìmoore hàn dípò ká máa ro èròkerò, tàbí ká mọ tara wa nìkan.”—Tamara.

Ìmọ̀ràn kan rèé: Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Ó máa rọrún fáwọn ọmọ láti máa dúpẹ́ tí wọ́n bá gbọ́ tó ò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn míì, tó o sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn náà.

a Látinú ìwé Thanks! How Practicing Gratitude Can Make You Happier.

Ohun táwọn òbí sọ

Jeffrey àti Karen.

“Èmi àti ìyàwó mi kọ́ àwọn ọmọ wa bí wọ́n ṣe lè kọ lẹ́tà ìdúpẹ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń mú káwọn ọmọ wa rántí pé kò pọn dandan káwọn míì fún wọn lẹ́bùn tàbí kí wọ́n ṣe nǹkan fún wọn. Ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó bá ṣoore fúnni.”—Jeffrey àti Karen ìyàwó rẹ̀.

Susan àti Christopher.

“Tó bá jẹ́ pé látìgbà táwọn ọmọ ti lè sọ pé ẹ jọ̀wọ́ àti ẹ ṣeun la ti ń kọ́ wọn pé kí wọ́n máa sọ bẹ́ẹ̀, ó máa rọrùn fún wọn láti máa dúpẹ́, wọ́n á sì di àgbà tó moore lẹ́yìn ọ̀la.”—Susan àti Christopher ọkọ rẹ̀.

Àtúnyẹ̀wò: Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Moore

  • Kọ́ wọn ni ohun tí wọ́n á sọ. Ẹ lè kọ́ àwọn ọmọdé pàápàá láti máa dúpẹ́ bí ẹnì kan bá fún wọn lẹ́bùn tàbí tó ṣe wọ́n lóore.

  • Kó wọn ní òun tí wọ́n á ṣe. Kọ́ àwọn ọmọ rẹ bí wọ́n ṣe lè kọ̀wé ìdúpẹ́ tí ẹnì kan bá fún wọn lẹ́bùn. Tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé, á jẹ́ kí wọ́n mọrírì bẹ́ẹ̀ ṣe ń sapá tó láti mú kí nǹkan máa lọ geerege nínú ìdílé.

  • Kọ́ wọn ni ìwà tí wọ́n á hù. Ìrẹ̀lẹ̀ á jẹ́ káwọn ọmọ rẹ̀ rí i pé àwọn ò lè ṣàṣeyọrí láìsí ìrànlọ́wọ́ àwọn míì, wọ́n á sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ràn wọ́n lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́