ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 97
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Tọrọ Àforíjì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Tọrọ Àforíjì?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o tọrọ àforíjì?
  • Bó o ṣe lè sọ pé “Máà bínú”
  • Ó Ha Yẹ Kí O Tọrọ Àforíjì Ní Tòótọ́ bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Bó O Ṣe Lè Tọrọ Àforíjì
    Jí!—2015
  • Èé Ṣe Tí Títọrọ Àforíjì Fi Ṣòro Tó Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Títọrọ Àforíjì Ọ̀nà Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ Láti Wá Àlàáfíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 97
Akẹ́kọ̀ọ́ kan tí olùkọ́ rẹ̀ ń bá wí wà lórí ìjókòó nínú kíláàsì.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Tọrọ Àforíjì?

Kí lo máa ṣe táwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀?

  1. Olùkọ rẹ bá ẹ wí torí pé o hùwà tí ò dáa nínú kíláàsì.

    Ṣé wàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ olùkọ́ rẹ​—tó o bá tiẹ̀ rò pé ṣe ló gba ọ̀rọ̀ náà sódì?

  2. Ọ̀rẹ́ rẹ gbọ́ pé o bú òun.

    Ṣé wàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ​—tó o bá tiẹ̀ gbà pé ohun tó o sọ ò burú?

  3. O bínú sí bàbá rẹ, o sì sọ̀rọ̀ àrífín sí i.

    Ṣé wàá tọrọ àforíjì lọ́wọ́ bàbá rẹ​—tó o bá tiẹ̀ gbà pé òun ló mú inú bí ẹ?

Bẹ́ẹ̀ ni ni ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ṣùgbọ́n kí nìdí tó fi yẹ kó o tọrọ àforíjì, tó o bá tiẹ̀ rò pé ọwọ́ ẹ kọ́ ni gbogbo ẹ̀bi wà?

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o tọrọ àforíjì?

  • Bó o ṣe lè sọ pé “Máà bínú”

  • Ohun tí àwọn ojúgbà rẹ sọ

Kí nìdí tó fi yẹ kó o tọrọ àforíjì?

  • Ẹni tó bá tọrọ àforíjì fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun. Tó o bá ń fi hàn pé o mọ ẹ̀bi rẹ lẹ́bi torí ohun tó o sọ tàbí torí ohun tó o ṣe, ò ń fi hàn pé o ti ń ní àwọn ànímọ́ pàtàkì tó o máa nílò tó o bá dàgbà.

    “Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti sùúrù lè mú ká tọrọ àforíjì ká sì wá tẹ́tí sí ohun tí ẹlòmíì fẹ́ sọ.”​—Rachel.

  • Tó o bá tọrọ àforíjì, á mú kó o lè ṣe àtúnṣe. Àwọn èèyàn tó bá ń sọ pé “Máà bínú” ń fi hàn pé àlàáfíà jẹ àwọn lógún ju kí wọ́n dá ara wọn láre tàbí kí wọ́n fi àṣìṣe ẹlòmíì hàn.

    “Tó ò bá tiẹ̀ rò pé ìwọ lo jẹ̀bi, bó o ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà ló yẹ kó jẹ ọ́ lógún. Kò ná èèyàn ní nǹkan kan láti sọ pé ‘Forí jì mí,’ ṣùgbọ́n ó lè tún ohun tó ti bà jẹ́ ṣe.”​—Miriam.

  • Tó o bá tọrọ àforíjì, ara máa tù ẹ́. Ẹrù tó wúwo láti gbé ni ẹ̀dùn ọkàn téèyàn máa ń ní tó bá sọ̀rọ̀ tàbí hùwà tí ò dáa sí ẹlòmíì. Ṣùgbọ́n, tó o bá tọrọ àforíjì, ó ti gbé ẹrù yẹn kúrò léjìká ẹ nìyẹn.a

    “Àwọn ìgbà míì wà tí mo máa ń fìbínú sọ̀rọ̀ sí màmá tàbí bàbá mi. Ó máa ń dùn mí, ṣùgbọ́n ó máa ń ṣòro fún mi láti tọrọ àforíjì. Àmọ́, tí mo bá tọrọ àforíjì, ará máa ń tù mí torí pé àlàáfíà á tún pa dà jọba nínú ilé.”​—Nia.

    Ọmọdékùnrin kan gbé àpáta ńlá sí ẹ̀yìn rẹ̀.

    Àbámọ̀ dà bí ẹrù tó wúwo; tó o bá ti tọrọ àforíjì, ẹrù yẹn ò sí lórí ẹ mọ́ nìyẹn

Ṣé òótọ́ ni kì í rọrùn láti tọrọ àforíjì? Bẹ́ẹ̀ ni! Dena, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ti ní láti tọrọ àforíjì léraléra torí pé ó hùwà tí ò dáa sí mọ́mì rẹ̀, sọ pé: “Kò rọrùn láti sọ pé ‘Ẹ máà bínú.’ Ṣe ni ọkàn mi máa ń bà jẹ́ tí mi ò sì ní lé sọ nǹkan kan!”

Bó o ṣe lè sọ pé “Máà bínú”

  • Tó bá ṣeé ṣe, tọrọ àforíjì ní ojúkojú. Tó o bá tọrọ àforíjì ní ojúkojú, onítọ̀hún á rí i pé tinútinú lo fi kábàámọ̀ ohun tó o ṣe. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé ṣe lo tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ láti fi bẹ̀ ẹ́, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rí bó ṣe dùn ẹ́ tó. Kódà, tó o bá fi àwòrán ojú tó fi ẹ̀dùn ọkàn hàn ránṣẹ́ pẹ̀lú àtẹ̀jíṣẹ́ náà, ó lè dà bíi pé ẹ̀bẹ̀ orí ahọ́n lásán ni, kò dénú ẹ.

    Ìmọ̀ràn: Tó ò bá lè tọrọ àforíjì ní ojúkojú, ó lè pè sórí fóònù tàbí kó o fi káàdì tó o kọ ọ̀rọ̀ sí ránṣẹ́. Ọ̀nà yòówù kó o gbà tọrọ àforíjì, mọ irú ọ̀rọ̀ tí wàá sọ.

    Ìlànà Bíbélì: “Ọkàn olódodo máa ń ṣe àṣàrò kí ó tó dáhùn.”​—Òwe 15:28.

  • Tètè tọrọ àforíjì. Tó ò bá tètè tọrọ àforíjì, ọ̀rọ̀ náà lè burú ju bó ṣe rí tẹ́lẹ̀ lọ, àárín ìwọ àti ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ ò sì ní gún.

    Ìmọ̀ràn: Ní àfojúsùn​—bí àpẹẹrẹ, ‘Màá tọrọ àforíjì lónìí.’ Pinnu ìgbà tó dáa jù lọ kó o ṣe bẹ́ẹ̀; má sì ṣe jẹ́ kí ọjọ́ yẹn yẹ̀.

    Ìlànà Bíbélì: “Tètè yanjú ọ̀rọ̀.”​—Mátíù 5:25.

  • Tọrọ àforíjì látọkàn wá. Tó o bá sọ pé: “Máà bínú pé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ nìyẹn” ìyẹn kì í ṣe ẹ̀bẹ̀! Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Janelle sọ pé: “Bí ẹni tó o ṣẹ̀ bá rí i pé o mọ ẹ̀bi rẹ lẹ́bi, ó máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.”

    Ìmọ̀ràn: Tọrọ àforíjì pátápátá. Má ṣe sọ pé, “Àwa méjèèjì la jọ lẹ̀bi, màá tọrọ àforíjì tèmi, kíwọ náà yáa tọrọ àforíjì tìẹ.”

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà.”​—Róòmù 14:19.

Ohun tí àwọn ojúgbà rẹ sọ

Valerie.

“Ó gba kéèyàn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kó tó lè tọrọ àforíjì, pàápàá jù lọ tí mo bá rò pé èmi nìkan kọ́ ló lẹ̀bi. Bó bá tiẹ̀ wá jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn, màá fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ tó dáa tó sì gbéni ró. Mo fẹ́ yanjú ìṣòro náà ni, kì í ṣe pé mo fẹ́ dá kún un.”​—Valerie.

Philip.

“Tó o bá fẹ́ láti tọrọ àforíjì, ìyẹn á fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ ọ́ lógún ju ti ara rẹ lọ. Ó lè tini lójú láti tọrọ àforíjì, ṣùgbọ́n á jẹ́ kó o dùn ún bá ṣọ̀rẹ̀ẹ́, ó sì lè mú kí àjọṣe yín túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́.”​—Philip.

Kendall.

“Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ṣe ni ẹni tó bínú gba ọ̀rọ̀ sódì. Ṣùgbọ́n ìyẹn ò fi hàn pé èmi ló làre ẹni yẹn ló sì lẹ̀bi. Ó sàn kéèyàn ro bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Bí ohun tí mo sọ tàbí ohun tí mo ṣe bá dun ẹnì kan, mo gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjì.”​—Kendall.

Àtúnyẹ̀wò: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Tọrọ Àforíjì?

  • Ẹni tó bá tọrọ àforíjì fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun.

  • Tó o bá tọrọ àforíjì, á mú kó o lè ṣe àtúnṣe.

  • Tó o bá tọrọ àforíjì, á mú kára tù ẹ́.

Bó o ṣe lè tọrọ àforíjì:

  • Tó bá ṣeé ṣe, tọrọ àforíjì ní ojúkojú.

  • Tètè tọrọ àforíjì.

  • Tọrọ àforíjì látọkàn wá.

a Tó o bá ba nǹkan ẹlòmíì jẹ́ tàbí tó o sọ ọ́ nù, ó máa dára bó o ṣe ń tọrọ àforíjì kó o wá bí wàá ṣe tún ohun tó o bà jẹ́ ṣe tàbí kó o sanwó ohun tó o sọ nù.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́