ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 100
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ṣàìgbọràn Sáwọn Òbí Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ṣàìgbọràn Sáwọn Òbí Mi?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí kò yẹ kó o ṣe
  • Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà ṣe é
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jẹ́ Káwọn Òbí Mi Fọkàn Tán Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ló Dé Táwọn Òbí Mi Ò Fẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù!
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Ò Fi Fọkàn Tán Mi?
    Jí!—2008
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 100
Àwọn òbí kan ń bá ọmọbìnrin wọn sọ̀rọ̀ torí pé ó kọjá aago tó yẹ kó wọlé.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ṣàìgbọràn Sáwọn Òbí Mi?

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo òbí ló máa ń fún àwọn ọmọ wọn lófin nínú ilé. Wọ́n lè ní òfin nípa aago tó yẹ kí àwọn ọmọ máa wọlé, iye àkókò tí wọ́n lè lò lórí ẹ̀rọ alágbèéká àti bí wọ́n ṣe ń hùwà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ká sọ pé o ṣàìgbọràn sí ọ̀kan nínú àwọn òfin yẹn ńkọ́? Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, síbẹ̀, o lè ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà burú ju bó ṣe yẹ lọ. Àpilẹ̀kọ yìí máa kọ́ ẹ bó o ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.

  • Ohun tí kò yẹ kó o ṣe

  • Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà ṣe é

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ohun tí kò yẹ kó o ṣe

  • Táwọn òbí ẹ ò bá mọ̀ pé o ti ṣe ohun kan tí kò dáa, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o má sọ̀rọ̀ náà síta.

  • Tí wọn ò bá mọ̀ pé o ti ṣàìgbọràn, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o wá àwáwí tàbí kó o di ẹ̀bi ru ẹlòmíì.

Kò sí èyí tó o ṣe nínú ẹ̀ tó dáa. Kí nìdí? Torí pé tó o bá bo ohun tó o sẹ mọ́lẹ̀ tàbí tí o kàn ń ṣàwáwí, ìyẹn máa fi hàn pé oò tíì dàgbà dénú. Ìyẹn máa jẹ́ káwọn òbí ẹ̀ máa wò ó pé oò tí mọ ohun tó tọ́ láti ṣe.

“Irọ́ ò lè yanjú ìṣòro rárá. Torí pé tó bá yá, àṣírí máa pa dà tú síta, ìyà téèyàn sì máa jẹ máa pọ̀ ju èyí tó máa jẹ tó bá ti sòótọ́ látilẹ̀.”—Diana.

Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà ṣe é

  • Gba ẹ̀bi ẹ lẹ́bi. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí.” (Òwe 28:13) Àwọn òbí ẹ mọ̀ pé o kì í ṣe ẹni pípé. Àmọ́ wọ́n fẹ́ kó o jẹ́ olóòótọ́.

    “Ó dájú pé àwọn òbí ẹ máa fàánú hàn sí ẹ tó o bá ń sòótọ́. Tó o bá jẹ́wọ́ ohun tó o ṣe, àwọn òbí ẹ á túbọ̀ fọkàn tán ẹ.”​—⁠Olivia.

  • Tọrọ àforíjì. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ gbé ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀.’ (1 Pétérù 5:⁠5) Ó gba ìrẹ̀lẹ̀ kéèyàn tó sọ pé “ẹ má bínú,” kéèyàn sì gbìyànjú láti má ṣe àwáwí kankan.

    “Tó bá ti mọ́ èèyàn lára láti máa ṣàwáwí, ńṣe ni onítọ̀hún máa ba ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ jẹ́. Tó bá yá, ẹ̀rí ọkàn náà ò ní dà á láàmú mọ́ tó bá ṣe ohun tí kò dáa.”—Heather.

  • Fara mọ́ ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ. Bíbélì sọ pé: “Fetí sí ìbáwí.” (Òwe 8:33) Má ṣe máa kùn tí wọ́n ba bá ẹ wí, fara mọ́ ohun tí àwọn òbí ẹ bá sọ.

    “Tó ò bá kí ń fara mọ́ ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ, ó máa mú kí nǹkan burú sí i. Gbìyànjú láti fara mọ́ ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ, dípò tí wàá fi máa ronú nípa àǹfààní tí wọ́n fi dù ẹ́.”—Jason.

  • Sapá láti ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, èyí tó bá ọ̀nà ìgbésí ayé yín ti tẹ́lẹ̀ mu.” (Éfésù 4:22) Bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà rere tó máa jẹ́ kí àwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ.

    “Tó o bá ń ṣe ìpinnu tó dáa, tó o sì ń ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ kí àwọn òbí ẹ ríi pé o ò ní ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, wọ́n á túbọ̀ fọkàn tán ẹ.”​—⁠Karen.

Àbá: Ṣe ju ohun táwọn òbí ẹ béèrè lọ́wọ́ ẹ, kí wọ́n lè mọ̀ pé ẹni tó ṣeé gbára lé ni ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jáde lọ síbì kan, pe àwọn òbí rẹ lórí fóònù kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ tó o bá ti ń bọ̀ nílé, kódà tó ò bá ní pẹ́ níta. Ìyẹn máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o fẹ́ káwọn túbọ̀ fọkàn tán ẹ.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Darius.

“Tó o bá fi òtítọ́ pa mọ́ fáwọn òbí ẹ, irọ́ lo pa yẹn. Nígbẹ̀yìn, àṣírí máa pa dà tú, tí wọ́n bá sì mọ̀, ìbáwí tí wọ́n máa fún ẹ máa pọ̀ ju èyí tí wọ́n máa fún ẹ tó bá jẹ́ pé àtìbẹ̀rẹ̀ lo ti sọ òótọ́.”​—Darius.

Sierra.

“Téèyàn bá ń di ẹ̀bi ohun tó ṣe lé ẹlòmíì lórí, ńṣe ló fi hàn pé onítọ̀hún ò tíì gbọ́n débi tó fi máa gba ẹ̀bi ẹ̀ ní ẹ̀bi. Àwọn òbí wa lè má fọkàn tán wa mọ́ tí wọ́n bá ríi pé a ò ṣe tán láti gba ẹ̀bi wa lẹ́bi, ká sì tọrọ àforíjì.”—Sierra.

Àtúnyẹ̀wò: Kí ni mo lè ṣe tí mo bá ṣàìgbọràn sáwọn òbí mi?

  • Gba ẹ̀bi ẹ lẹ́bi. Àwọn òbí ẹ mọ̀ pé o kì í ṣe ẹni pípé. Ṣáà sapá láti jẹ́ olóòótọ́, ṣé wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Tọrọ àforíjì. Sọ pé “Ẹ má bínú,” jẹ́ kó wá látọkàn, sì gbìyànjú láti má ṣe àwáwí.

  • Fara mọ́ ìbáwí tí wọ́n bá fún ẹ. Fara mọ́ ìbáwí èyíkéyìí táwọn òbí ẹ bá fún ẹ.

  • Sapá láti ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ. Bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà rere tó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fọkàn tán ẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́