ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 106
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Àárín Èmi àti Olùkọ́ Mi Lè Gún?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Àárín Èmi àti Olùkọ́ Mi Lè Gún?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Olùkọ́ tó burú
  • Ohun tó o máa ṣe kó o lè fara dà á
  • Bó ṣe yẹ kó o bá olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kó Má Bàa Sí Wàhálà Láàárín Èmi àti Olùkọ́ Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Àwọn Olùkọ́—Èé Ṣe Tá A Fi Nílò Wọn?
    Jí!—2002
  • Kò Retí Pé Òun Á Ṣàṣeyọrí Tó Tóyẹn
    Jí!—2003
  • Kí Ló Ń Mú Káwọn Èèyàn Máa Ṣe Iṣẹ́ Olùkọ́?
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 106
Olùkọ́ kan ń bá ọ̀dọ́bìnrin kan wí lójú àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Àárín Èmi àti Olùkọ́ Mi Lè Gún?

  • Olùkọ́ tó burú

  • Ohun tó o máa ṣe kó o lè fara dà á

  • Bó ṣe yẹ kó o bá olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Olùkọ́ tó burú

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń ní olùkọ́ kan tó dà bíi pé ó burú, tó máa mú ayé súni, tàbí tí kó láàánú rárá.

  • Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21) kan tó ń jẹ́ Luis sọ pé: “Mo ní olùkọ́ kan tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló máa ń sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ó sì máa ń hùwà tí kò dáa sí wọn. Olùkọ́ náà mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ fẹ̀yìn tì nídìí iṣẹ́, ìdí nìyẹn tọ́kàn ẹ̀ fi balẹ̀ pé wọn ò lè lé òun lẹ́nu iṣẹ́.”

  • Melanie tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25) rántí bí olùkọ́ rẹ̀ ṣe dájú sọ ọ́. Ó ní: “Olùkọ́ náà sọ pé ìdí tóun fi ń hùwà tí kò dáa sí mi ni pé kì í ṣe ọ̀kan lára ẹ̀sìn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ni mò ń ṣe. Ó sọ pé kí n yáa fi kọ́ra torí pé wọ́n ṣì máa hùwà àìdáa sí mi tí mo bá dàgbà.”

Tó o bá ní olùkọ́ tó jọ pé ó burú, má ṣe ro ara ẹ pin. Gbìyànjú àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Ohun tó o máa ṣe kó o lè fara dà á

  • Mú ara ẹ bá ipò tó o wà mu. Ohun tí olùkọ́ kọ̀ọ̀kan máa ń fẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe máa ń yàtọ̀ síra. Torí náà, sapá kó o lè mọ ohun tí olùkọ́ rẹ̀ fẹ́ kó o ṣe, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ṣègbọràn.

    Ìlànà Bíbélì: “Ọlọ́gbọ́n máa ń fetí sílẹ̀, á sì kọ́ ẹ̀kọ́ sí i.”​—Òwe 1:5.

    “Mo rí i pé tí n bá fẹ́ múnú olùkọ́ mi dùn, àfi kí n ṣe nǹkan lọ́nà ó fẹ́, mo sì sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó mú kí àlàáfíà wà láàárín wa nìyẹn.”​—Christopher.

  • Máa bọ̀wọ̀ fúnni. Rí i pé o bọ̀wọ̀ fáwọn olùkọ́ rẹ tó o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀. Má ṣe rí wọn fín kódà tó o bá rò pé ohun tó tọ́ sí wọn nìyẹn. Rántí pé ẹ kì í ṣe ẹgbẹ́, akẹ́kọ̀ọ́ wọn lọ jẹ́.

    Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín máa jẹ́ ọ̀rọ̀ onínúure, tí iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bó ṣe yẹ kí ẹ dá ẹnì kọ̀ọ̀kan lóhùn.”​—Kólósè 4:6.

    “Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kì í sábà bọ̀wọ̀ fáwọn olùkọ́ bó ṣe yẹ, torí náà bó o ṣe ń sapá láti bọ̀wọ̀ fáwọn olùkọ́ ẹ lè mú kí wọ́n máa hùwà tó dáa sí ẹ.”​—Ciara.

  • Máa gba tẹni rò. Èèyàn làwọn olùkọ́ náà. Ìyẹn ni pé bíi ti gbogbo wa, àwọn náà níṣòro, wọ́n sì máa ń ṣàníyàn. Torí náà, má kàn ronú pé, ‘Olùkọ́ mi ti le koko jù’ tàbí pé ‘Olùkọ́ mi kórìíra mi.’

    Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo wa ni a máa ń ṣàṣìṣe.”​—Jémíìsì 3:​2, àlàyé ìsàlẹ̀.

    “Iṣẹ́ táwọn olùkọ́ ń ṣe ò rọrùn rárá. Ẹ wo bó ṣe máa nira tó fún olùkọ́ kan láti mú káwọn ọmọdé fara balẹ̀ kó sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ó máa ń ṣe mí bíi kí n mú nǹkan rọrùn fún olùkọ́ bẹ́ẹ̀ kí n má sì dá kún wàhálà rẹ̀.”​—Alexis.

  • Bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀. Àwọn òbí ẹ ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ jù. Wọ́n fẹ́ kó o ṣàṣeyọrí nílé ìwé, ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ máa jẹ́ kó o lè fara dà á tó bá dà bíi pé olùkọ́ ẹ burú.

    Ìlànà Bíbélì: “Láìsí ìfinúkonú, èrò á dasán.”​—Òwe 15:22.

    “Àwọn òbí rẹ nírìírí jù ẹ́ lọ, wọ́n sì ti yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó le ju èyí tó o ti yanjú lọ. Torí náà, fetí sí ìmọ̀ràn wọn kó o lè ṣàṣeyọrí.”​—Olivia.

Bó ṣe yẹ kó o bá olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀

Nígbà míì, o lè sọ fún olùkọ́ rẹ nípa ìṣòro tó o máa ń ní pẹ̀lú ẹ̀. Tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, rántí pé ẹ kàn fẹ́ jọ sọ̀rọ̀ ni kì í ṣe pé ẹ fẹ́ bá ara yín jiyàn. Ó sì lè yà ẹ́ lẹ́nu pé ìjíròrò náà lè rọrùn, kó sì gbéṣẹ́.

Ìlànà Bíbélì: “Máa lépa àwọn ohun tó ń mú kí àlàáfíà wà.”​—Róòmù 14:19.

“Tó bá dà bíi pé ìwọ nìkan ni olùkọ́ rẹ ń fayé ni lára, béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ bóyá o ti ṣe ohun kan tó bí i nínú. Ìdáhùn rẹ̀ lè jẹ́ kó o mọ bó o lè ṣe ṣàtúnṣe.”​—Juliana.

“Ó lè jẹ́ ohun tó máa dáa jù ni pé kó o fara balẹ̀ ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún olùkọ́ ẹ níwọ àtiẹ̀ nìkan ṣáájú tàbí lẹ́yìn tẹ́ ẹ parí kíláàsì. Ó ṣeé ṣe kó gba tìẹ rò, ó sì máa mọrírì bó o ṣe yanjú ọ̀rọ̀ náà.”​—Benjamin.

OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN

“Ìgbà kan wà tí mi ò ṣe dáadáa nílé ìwé, olùkọ́ mi ò sì ṣe ohunkóhun láti ràn mí lọ́wọ́. Mi ò fẹ́ lọ sílé ìwé mọ́ torí olùkọ́ mi ti mú káyé sú mi.

“Mo lọ sọ́dọ̀ olùkọ́ míì kó lè fún mi nímọ̀ràn. Ohun tó sọ fún mi ni pé: ‘Olùkọ́ ẹ ò mọ̀ ẹ́ dáadáa, ìwọ náà ò sì mọ̀ ọ́n. Ó yẹ kó o sọ fún un pé o níṣòro. Ó lè jẹ́ ìwọ lo máa ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù tó ń bẹ̀rù láti bá a sọ̀rọ̀ lọ́wọ́.’

“Kò wù mí kí n ṣe bẹ́ẹ̀! Àmọ́, mo ronú lórí ohun tó sọ, mo sì rí i pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni. Tí mo bá fẹ́ kí nǹkan yàtọ̀, èmi ló yẹ kí n gbé ìgbésẹ̀.

“Lọ́jọ́ kejì, mo lọ bá olùkọ́ mi, mo sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún un pé mo máa ń gbádùn bó ṣe ń kọ́ wa gan-an, mo sì fẹ́ mọ púpọ̀ sí i lọ́dọ̀ rẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tí ò yé mi, mi ò sì mọ ohun tí mo lè ṣe. Ó wá sọ àwọn ohun tó mo lè ṣe, ó tiẹ̀ gbà láti ràn mí lọ́wọ́ lẹ́yìn iṣẹ́ kíláàsì tàbí nípasẹ̀ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà.

“Ó yà mí lẹ́nu! Ìjíròrò yẹn ti mú kí àárín èmi àti olùkọ́ mi túbọ̀ gún, ìyẹn sì mú kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti gbádùn ilé ìwé.”​—Maria.

Maria ń bá olùkọ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ kíláàsì.

Àbá: Tó bá dà bíi pé olùkọ́ ẹ ń fayé ni ẹ́ lára, kà á sí àǹfààní láti kọ́ ohun kan tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá dàgbà. Katie tó jẹ́ mọ ọdún méjìlélógún (22) sọ pé: “Lẹ́yìn tó o bá parí ilé ìwé, wàá ṣì pàdé àwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ tí kò láàánú. Tó o bá lè fara da olùkọ́ tó le nísinsìnyí, wàá lè fara da àwọn míì tó lè fayé sú ẹ lọ́jọ́ iwájú.”

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Jayza.

“Ọ̀pọ̀ ìgbà ni olùkọ́ kan máa ń múnú bí mi. Àmọ́, ìyá mi máa ń jẹ́ kí n ronú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn olùkọ́ mi. Ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ máa gba tàwọn olùkọ́ mi rò.”​—Jayza.

Victor.

“Kò dìgbà tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan ká tó bọ̀wọ̀ fún un. Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn olùkọ́ ń ṣe, ó sì yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn. Torí náà, ká tiẹ̀ sọ pé olùkọ́ kàn burú, bó o ṣe ń bọ̀wọ̀ fún un lè mú kó ronú, kíyẹn sì mú kó yíwà pa dà.”​—Victor.

Julia.

“Bí olùkọ́ ẹ bá tiẹ̀ burú, tó o bá níwà tútù, tó o sì ń bọ̀wọ̀ fúnni, ṣe lò ń fi hàn pé o nírẹ̀lẹ̀, o kì í sì yájú sáwọn èèyàn. Ó ṣeé ṣe kíyẹn mú kí olùkọ́ rẹ túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ẹ, kó sì mú nǹkan rọrùn fún ẹ.”​—Julia.

Àtúnyẹ̀wò: Kí ni mo lè ṣe kí àárín èmi àti olùkọ́ mi lè gún?

  • Mú ara ẹ bá ipò tó o wà mu. Rí i pé o lóye ohun tí olùkọ́ rẹ fẹ́ kó o ṣe, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ṣègbọràn.

  • Máa bọ̀wọ̀ fúnni. Rántí pé akẹ́kọ̀ọ́ ni ẹ́, torí náà rí i pé ò ń sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, má sì sọ̀rọ̀ àrífín.

  • Máa gba tẹni rò. Iṣẹ́ tó nira gan-an làwọn olùkọ́ ń ṣe. Máa ṣe sùúrù pẹ̀lú wọn.

  • Bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ ìrírí ni wọ́n ní nípa bá a ṣe lè bá àwọn èèyàn lò.

  • Bá olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀. Ní kí olùkọ́ ẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́, àmọ́ fara balẹ̀ sọ̀rọ̀, má sì bá a jiyàn. Jẹ́ kó mọ̀ pé ṣe lo fẹ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́