ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 107
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Mú Kí N Ṣèṣekúṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Mú Kí N Ṣèṣekúṣe?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Irọ́ àti òótọ́
  • Bó o ṣe lè borí ìṣekúṣe
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìbálòpọ̀?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ṣé A Lè Ka Fífi Ẹnu Lá Ẹ̀yà Ìbímọ Ẹlòmíì sí Ìbálòpọ̀?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Fi Ìbálòpọ̀ Lọ̀ Mí?
    Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 107
Ọ̀dọ́kùnrin kan tó mú fóònù rẹ̀ dání nínú yàrá ìmúra, táwọn ọ̀dọ́kùnrin yòókù ń sọ fún pé kó ṣe ìpinnu.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Mi Mú Kí N Ṣèṣekúṣe?

“Nígbà tí mo wà níléèwé, bí ẹnì kan bá sọ pé òun ti ní ìbálòpọ̀ rí, á ṣe àwa yòókù bíi pé kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀ ká má bàa gbẹ́yìn. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tó fẹ́ kí tòun yàtọ̀.”​—Elaine, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21].

Ṣó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé kó o ní ìbálòpọ̀​—torí pé ó jọ pé gbogbo èèyàn ló ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Ṣó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé kó o ní ìbálòpọ̀ torí pé ẹnì kan tó o fẹ́ràn ń fẹ́ kẹ́ ẹ jọ ní ìbálòpọ̀?

Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ káwọn míì tàbí ìfẹ́ ọkàn rẹ má bàa mú kó o ṣèṣekúṣe, á sì jẹ́ kó o lè ṣe yíyàn tó dáa.

  • Irọ́ àti òótọ́

  • Bó o ṣe le borí ìṣekúṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà rẹ sọ

Irọ́ àti òótọ́

IRỌ́: Gbogbo èèyàn ló ń ní ìbálòpọ̀ (àfi èmi).

ÒÓTỌ́: Nínú ìwádìí kan, méjì lára àwọn ọmọ ọdún méjìdínlógún mẹ́ta tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé àwọn ti ní ìbálòpọ̀ rí. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, àwọn tó pọ̀ ni ò tíì ní ìbálòpọ̀, kódà wọ́n ju ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá lọ tí ò tíì ní ìbálòpọ̀. Kì í ṣe “gbogbo èèyàn” ló ń ní ìbálòpọ̀.

IRỌ́: Ìbálòpọ̀ á jẹ́ kí àjọṣe wa sunwọ̀n sí i.

ÒÓTỌ́: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin kan lè máa sọ bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè mú kí obìnrin kan ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn, irọ́ tó jìnnà sóòótọ́ nìyẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ni ọkùnrin máa ń já obìnrin jù sílẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí inú obìnrin tó rò pé ọkùnrin náà nífẹ̀ẹ́ òun kò sì ní já òun kulẹ̀, á sì wá bà jẹ́.a

IRỌ́: Bíbélì sọ pé ìbálòpọ̀ ò dáa.

ÒÓTỌ́: Bíbélì jẹ́ ká ní èrò tó dáa nípa ìbálòpọ̀ ṣùgbọ́n ó sọ pé ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló lè ní ìbálòpọ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 1 Kọ́ríńtì 7:3.

IRỌ́: Ìgbésí ayé á nira fún mi tí mo bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì.

ÒÓTỌ́: Tó o bá dúró dìgbà tó o ṣègbéyàwó kó o tó ní ìbálòpọ̀, wàá túbọ̀ láyọ̀ torí pé, o ò ní ní ìdààmú, àbámọ̀ àti àìbalẹ̀ ọkàn táwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó máa ń ní.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Dídúró di ẹ̀yìn ìgbéyàwó kéèyàn tó ní ìbálòpọ̀ kò pa ẹnikẹ́ni lára rí. Ṣùgbọ́n níní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ti ṣèpalára tó pọ̀.

Bó o ṣe lè borí ìṣekúṣe

  • Túbọ̀ kórìíra ohun tí kò tọ́. Bíbélì sọ pé àwọn tó dàgbà “ti kọ́ agbára ìfòyemọ̀ wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Wọ́n mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́, torí náà wọn ò jẹ́ gbà láti ṣèṣekúṣe.

    “Mò ń sapá gidigidi láti ṣe ohun tó tọ́ kí n sì ní orúkọ rere, mi ò sì ní ṣe ohun tó máa bà mí lórúkọ jẹ́.”​—Alicia, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16].

    Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí lo fẹ́ káwọn èèyàn máa sọ nípa ẹ? Ṣó wá yẹ kó o gbàgbé nípa ìyẹn kó o lè rí ojúure ẹlòmíì?

  • Ro ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. Bíbélì sọ pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.” (Gálátíà 6:7) Ronú nípa ìyípadà tó ṣeé ṣe kó bá ìgbésí ayé rẹ àti ti onítọ̀hún tó o bá gbà pé kó bá ẹ lò pọ̀.b

    “Ọkàn àwọn tó ń bára wọn lò pọ̀ láìṣègbéyàwó máa ń dá wọn lẹ́bi, wọ́n máa ń kábàámọ̀, wọ́n sì máa ń rò pé àwọn ti dẹni ẹ̀tẹ́​—ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé wọ́n lé lóyún ẹ̀sín tàbí àrùn téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀.”​—Sienna, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16].

    Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ìwé Sex Smart béèrè pé: “Bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ń sún ẹ pé kó o ṣe ohun tó lè kó ẹ sí wàhálà, ṣé irú àwọn tó yẹ kó o máa bá rìn nìyẹn, ṣé ìmọ̀ràn wọn ló sì yẹ kó o máa tẹ́tí sí?”

  • Ní èrò tó tọ́. Kò sí ohun tó burú nínú ìbálòpọ̀. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé kí àwọn méjì tó jọ ṣègbéyàwó máa gbádùn ìbálòpọ̀.​—Òwe 5:​18, 19.

    “Ìbálòpọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun rere tí Ọlọ́run dá. Ṣùgbọ́n àwọn tí Ọlọ́run ṣètò rẹ̀ fún nìkan ló fẹ́ kí wọ́n máa gbádùn rẹ̀, ìyẹn àwọn tó ti ṣègbéyàwó.”​—Jeremy, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17].

    Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Tó o bá ṣègbéyàwó lọ́jọ́ kan, ìwọ náà á lè ní ìbálòpọ̀. Wàá sì lè gbádùn rẹ̀ dáadáa, láìsí irú àwọn àbájáde búburú tá a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ̀ yìí.

a Ṣùgbọ́n ọkùnrin nìkan kọ́ ló máa ń rọ obìnrin pé kó bá òun lò pọ̀ o. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn obìnrin ló máa ń mú kí àwọn ọkùnrin bá àwọn lò pọ̀.

b Lára ohun tó lè yọrí sí ní oyún ẹ̀sín, bí ọjọ́ orí àwọn tó bára wọn lò pọ̀ bá ṣe rí sì tún lé mú kí wọ́n rú òfin tó kan níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọmọdé.

Ohun tí àwọn ojúgbà rẹ sọ

Mikayla.

“Kéèyàn ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó kọ́ ni ọ̀nà téèyàn ń gbà fi ìfẹ́ hàn sí ẹnì kan. Béèyàn ṣe ń fìfẹ́ hàn ni pé kí ọ̀wọ̀ tó ní fún ara rẹ̀ àti onítọ̀hún mú kó dúró títí tí wọ́n á fi ṣègbéyàwó. Ìgbéyàwó máa ń fọkàn ẹni balẹ̀ torí á jẹ́ kó o mọ̀ pé torí ìbálòpọ̀ kọ́ ni ẹnì kejì rẹ fi fẹ́ràn rẹ.”—Mikayla.

Caiman.

“Àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó máa ń jára wọn kulẹ̀. Ohun tó tiẹ̀ wọ́pọ̀ ni pé lẹ́yìn ìbálòpọ̀ kí wọ́n da ẹni kejì wọn nù bí omi ìṣanwọ́. Ìgbádùn èyíkéyìí téèyàn bá ní nínú irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ kì í tọ́jọ́, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í sì í dáa.”—Caiman.

Àtúnyẹ̀wò: Báwo ni mo ṣe lè borí ìṣekúṣe?

  • Túbọ̀ kórìíra ohun tí kò tọ́. Bí ẹnì kan bá mọ ohun tó tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́, kò ní gbà láti ṣèṣekúṣe.

  • Ro ohun tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. Ronú nípa ìyípadà tó ṣeé ṣe kó bá ìgbésí ayé rẹ àti ti onítọ̀hún tó o bá gbà pé kó bá ẹ lò pọ̀.

  • Ní èrò tó tọ́. Kò sí ohun tó burú nínú ìbálòpọ̀. Ṣùgbọ́n ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jọ jẹ́ ọkọ àti aya nìkan ni Ọlọ́run ṣe é fún.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́