ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 2: Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ fún Ìrìbọmi
Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, tó o sì ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, ó dájú pé wàá tí máa ronú nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Àmọ́, báwo lo ṣe máa mọ̀ pé o ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi?a
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Báwo ni nǹkan tí mo mọ̀ ṣe gbọ́dọ̀ pọ̀ tó?
Tó o bá ń múra láti ṣèrìbọmi, kò pọn dandan kó o máa há ohun tó ò ń kọ́ sórí bí ìgbà tó ò ń múra ìdánwò nílé ìwé. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ lo “agbára ìrònú” rẹ kó lè túbọ̀ dá ẹ lójú pé òtítọ́ làwọn ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì. (Róòmù 12:1) Bí àpẹẹrẹ:
Ṣé ó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wà àti pé òun ló yẹ kó o máa sìn?
Bíbélì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.”—Hébérù 11:6.
Bi ara ẹ pé: ‘Kí ló mú kí n gba Ọlọ́run gbọ́?’ (Hébérù 3:4) ‘Kí nìdí tó fi jẹ́ pé òun ló yẹ kí n máa sìn?’—Ìfihàn 4:11.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ẹ̀kọ́ Ẹfolúṣọ̀n Tọ̀nà àbí Ẹlẹ́dàá Kan Wà?—Apá 1: Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé Ọlọ́run wà?”
Ṣé ó dá ẹ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì lóòótọ́?
Bíbélì sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì wúlò fún kíkọ́ni, fún bíbáni wí, fún mímú nǹkan tọ́, fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo”—2 Tímótì 3:16.
Bi ara ẹ pé: ‘Kí ló mú kí n gbà pé èrò èèyàn kọ́ ló wà nínú Bíbélì?’—Àìsáyà 46:10; 1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá Kìíní: Wo Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì.”
Ṣé ó dá ẹ lójú pé ìjọ Kristẹni ni Jèhófà ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ?
Bíbélì sọ pé: “[Ọlọ́run] ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ nípasẹ̀ ìjọ àti nípasẹ̀ Kristi Jésù títí dé gbogbo ìran láé àti láéláé.”—Éfésù 3:21.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn nǹkan tá à ń gbọ́ láwọn ìpàdé Kristẹni ti ń wá, kì í ṣe ọ̀dọ̀ èèyàn?’ (Mátíù 24:45) ‘Ṣé mo máa ń lọ sípàdé déédéé, kódà táwọn òbí mi ò bá lè lọ (tí wọ́n bá gbà ẹ́ láyè láti máa lọ)?’—Hébérù 10:24, 25.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba?”
Kí ló yẹ kí n máa ṣe?
Kò dìgbà tó o bá di ẹni tó pé kó o tó lè ṣèrìbọmi. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o fẹ́ “jáwọ́ nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe rere” (Sáàmù 34:14) Bí àpẹẹrẹ:
Ṣé o máa ń fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nígbèésì ayé rẹ?
Bíbélì sọ pé: “Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn rere”—1 Pétérù 3:16.
Bi ara ẹ pé: ‘Àwọn nǹkan wo ni mo ti ṣe tó fi hàn pé mo ti “kọ́ agbára ìfòyemọ̀” mi, kí n lè máa “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́”?’ (Hébérù 5:14) ‘Ṣé mo lè rántí àwọn ìgbà kan táwọn ojúgbà mi fẹ́ kí n ṣe ohun tí ò dáa, àmọ́ tí mo kọ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́? Ṣé àwọn tó máa ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́ ni mo yàn lọ́rẹ̀ẹ́?’—Òwe 13:20.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Mi?”
Ṣé o mọ̀ pé gbogbo ohun tó o bá ṣe lo máa jíhìn fún Jèhófà?
Bíbélì sọ pé: “Kálukú wa ló máa jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run”—Róòmù 14:12.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mi ò kì í tan ara mi jẹ, ṣe mo sì jẹ́ olóòótọ́ nínú àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn èèyàn?’ (Hébérù 13:18) ‘Tí mo bá ṣe ohun tí ò dáa, ṣé mo máa ń gbà pé mo jẹ̀bi, ṣé kì í ṣe pé mo máa ń dọ́gbọ́n bo ohun tí mo ṣe mọ́lẹ̀ àbí kí n di ẹ̀bi ẹ̀ ru àwọn ẹlòmíì?’—Òwe 28:13.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Mo Lè Ṣe Nípa Àwọn Àṣìṣe Mi?”
Ṣé ò ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?
Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín”—Jémíìsì 4:8
Bi ara ẹ pé: ‘Kí làwọn nǹkan tí mò ń ṣe kí n lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?’ Bí àpẹẹrẹ, ‘Ṣé mo máa ń ka Bíbélì déédéé?’ (Sáàmù 1:1, 2) ‘Ṣé mo máa ń gbàdúrà déédéé?’ (1 Tẹsalóníkà 5:17) ‘Tí mo bá ń gbàdúrà, ṣé mo máa ń sọ àwọn nǹkan pàtó tí mo fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún mi? Ṣé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni mò ń bá ṣọ̀rẹ́?’—Sáàmù 15:1, 4.
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?—Apá Kejì: Jẹ́ Kí Bíbélì Gbádùn Mọ́ Ẹ” àti “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà?”
ÀBÁ: Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó yẹ kó o ṣe láti múra sílẹ̀ fún ìrìbọmi, ka orí 37 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá 2. Ní pàtàkì wo àpótí tá a pè ní “Ṣó O Ti Ń Ronú Láti Ṣèrìbọmi?” tó wà lójú ìwé 308 sí 309.
a Kó o lè mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara ẹ sí mímọ́ kó o sì ṣèrìbọmi àti ìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 1.”