ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 111
  • Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 3: Kí Ló Ń Dá Mi Dúró?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?—Apá 3: Kí Ló Ń Dá Mi Dúró?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Tí mo bá lọ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lẹ́yìn ìrìbọmi ńkọ́?
  • Tó bá jẹ́ pé ojúṣe tí mo máa ní lẹ́yìn ìrìbọmi ló ń bà mí lẹ́rù ńkọ́?
  • Tó bá ń ṣe mí bíi pé kì í ṣe irú mi ló ń sin Jèhófà ńkọ́?
  • Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìrìbọmi Ló Máa Fìdí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Múlẹ̀
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Béèyàn Ṣe Lè Dẹni Tó Yẹ Fún Ìrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìrìbọmi​—Ohun Tó Yẹ Kí Gbogbo Kristẹni Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 111
Ọkùnrin kan ń ṣèrìbọmi nínú odò, àwọn míì sì ń wò ó láti etí odò náà.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Apá 3: Kí Ló Ń Dá Mi Dúró?

Ṣé ẹ̀rù ń bà ẹ́ láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o sì ṣèrìbọmi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí ìbẹ̀rù ẹ.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

  • Tí mo bá lọ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lẹ́yìn ìrìbọmi ńkọ́?

  • Tó bá jẹ́ pé ojúṣe tí mo máa ní lẹ́yìn ìrìbọmi ló ń bà mí lẹ́rù ńkọ́?

  • Tó bá ń ṣe mí bíi pé kì í ṣe irú mi ló ń sin Jèhófà ńkọ́?

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Tí mo bá lọ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lẹ́yìn ìrìbọmi ńkọ́?

Kí ló lè mú kó o ronú bẹ́ẹ̀: Ó ṣeé ṣe kó o mọ ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n sì yọ lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:​11-13) Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà.

“Ṣe lẹ̀rù ń bà mí pé màá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lẹ́yìn tí mo bá ṣèrìbọmi. Ọkàn mi ò balẹ̀ torí mo mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa kó ìtìjú bá àwọn òbí mi gan-an.”​—Rebekah.

Ohun tí Bíbélì sọ: “Kí èèyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ . . . Kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tó máa ṣàánú rẹ̀, sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, torí ó máa dárí jini fàlàlà.”​—Àìsáyà 55:7.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ò bá ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ, Jèhófà máa ń ṣàánú àwọn tó bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì gba ìbáwí tí wọ́n bá fún wọn.​—Sáàmù 103:​13, 14; 2 Kọ́ríńtì 7:11.

Ohun kan ni pé: Bó o tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, o lè borí ìdẹwò tó o bá gbára lé Jèhófà. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ó ṣe tán, ìwọ fúnra ẹ lo máa pinnu ohun tó o máa ṣe, kì í ṣe ẹlòmíì.

“Ṣe lẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí pé mo lè ṣàṣìṣe lẹ́yìn tí mo bá ṣèrìbọmi, àmọ́ mo wá rí i pé àṣìṣe ńlá ló máa jẹ́ tí mo bá fà sẹ́yìn láti ṣèrìbomi. Àti pé kò yẹ kí n jẹ́ káwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú dí mi lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́ nísinsìnyí.”​—Karen.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Bíi ti ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà, o lè borí ìdẹwò èyíkéyìí tó o bá pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—Fílípì 2:12.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ Ìdẹwò?”

Tó bá jẹ́ pé ojúṣe tí mo máa ní lẹ́yìn ìrìbọmi ló ń bà mí lẹ́rù ńkọ́?

Kí ló lè mú kó o ronú bẹ́ẹ̀: Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ti fi tẹbítọ̀rẹ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì kó lọ síbi tó jìnnà torí àtiṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. O wá ń ṣàníyàn pé àwọn èèyàn lè máa retí pé kíwọ náà gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.

“Ọ̀pọ̀ àǹfààní làwọn Kristẹni tó bá ti ṣèrìbọmi máa ń ní láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, àmọ́ àwọn kan ò ṣe tán láti yọ̀ǹda ara wọn tàbí kó jẹ́ pé ipò wọn ò fàyè gbà wọ́n.”​—Marie.

Ohun tí Bíbélì sọ: “Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.”​—Gálátíà 6:4.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Dípò tí wàá fi máa fi ara ẹ wé àwọn míì, á dáa kó o ronú lórí ohun tó wà nínú Máàkù 12:30 tó sọ pé: ‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.’

Kíyè sí pé ó yẹ kó o sin Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn ẹ, kì í ṣe ti ẹlòmíì. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wàá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀.

“Òótọ́ ni pé ìrìbọmi kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré, síbẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira. Tó bá jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ gidi lò ń bá kẹ́gbẹ́, wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó o bá nílò wọn. Tó o bá wá láǹfààní iṣẹ́ ìsìn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wàá láyọ̀ gan-an. Àmọ́ tó o bá ń sá láti ṣèrìbọmi, ara ẹ lò ń ṣe.”​—Julia.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá túbọ̀ mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí ẹ, ìyẹn á mú kó wù ẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe fún un.​—1 Jòhánù 4:19.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo “How Responsible Am I?” lédè Gẹ̀ẹ́sì

Tó bá ń ṣe mí bíi pé kì í ṣe irú mi ló ń sin Jèhófà ńkọ́?

Kí ló lè mú kó o ronú bẹ́ẹ̀: Àwa èèyàn kéré gan-an ní ìfiwéra pẹ̀lú Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Torí náà, o lè máa ronú pé bóyá ni Jèhófà rí tìẹ rò.

“Torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí mi, ó ń ṣe mí bíi pé mo ‘jogún’ àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà látọ̀dọ̀ wọn àti pé Jèhófà ò dìídì fà mí sọ́dọ̀ rẹ̀.”​—Natalie.

Ohun tí Bíbélì sọ: “Kò sí èèyàn tó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba tó rán mi fà á.”​—Jòhánù 6:44.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ti pé ò ń ronú nípa ìrìbọmi fi hàn pé Jèhófà ń fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀, ó sì fẹ́ kó o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun. Torí náà, ṣé kò ní dáa kíwọ náà gbé ìgbésẹ̀ kó o lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀?

Má gbàgbé pé Jèhófà ló ń pinnu ẹni tóun máa fà sọ́dọ̀ ara ẹ̀, kì í ṣe ìwọ tàbí ẹlòmíì. Bíbélì sì jẹ́ kó dá wa lójú pé tá a bá ‘sún mọ́ Ọlọ́run, òun náà á sún mọ́ wa.’​—Jémíìsì 4:8.

“Ti pé o mọ Jèhófà àti pé ó fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí náà, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò yẹ lẹ́ni tó ń sìn ín, rántí pé ojú yẹn kọ́ ni Jèhófà fi ń wò ẹ́. Ojú tí Jèhófà fi ń wò ẹ́ ló sì ṣe pàtàkì jù.”​—Selina.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá ti ń ṣe àwọn ohun tí Bíbélì ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi, á jẹ́ pé o kúnjú ìwọ̀n láti sin Jèhófà nìyẹn. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà lẹni tó yẹ kó o máa sìn.​—Ìfihàn 4:11.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà?”

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Skye.

“Má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù pé o lè ṣàṣìṣe dá ẹ dúró láti ṣèrìbọmi. Ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń sá eré ìje kan. O lè pinnu pé o ò ní sáré torí pé ẹ̀rù ń bà ẹ́ pé wàá ṣubú. Àmọ́ tó o bá ṣubú, o ṣì lè dìde. Òótọ́ kan ni pé o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ eré ìje kan kó o tó lè parí ẹ̀.”​—Skye.

Vinicio.

“Èèyàn ò ní tìtorí pé òun lè ní ìjàǹbá ọkọ̀ kó wá pinnu pé òun ò ní gba ìwé ìwakọ̀. Bí ọ̀rọ̀ ìrìbọmi ṣe rí náà nìyẹn. Ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà dípò ká máa da ara wa láàmú nípa ohun tá a ronú pé ó lè ṣẹlẹ̀.”​—Vinicio.

Àtúnyẹ̀wò: Kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?

  • Ìbẹ̀rù pé mo lè dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì. Bíi ti ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà, o lè borí ìdẹwò èyíkéyìí tó o bá pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀.

  • Ìbẹ̀rù àwọn ojúṣe tí mo máa ní. Tó o bá túbọ̀ mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí ẹ, ìyẹn á mú kó wù ẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe fún un.

  • Ìbẹ̀rù pé mi ò kúnjú ìwọ̀n láti sin Jèhófà. Tó o bá ti ń ṣe àwọn ohun tí Bíbélì ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi, á jẹ́ pé o kúnjú ìwọ̀n láti sin Jèhófà nìyẹn. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà lẹni tó yẹ kó o máa sìn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́