ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 114
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ayé Bá Sú Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ayé Bá Sú Mi?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mó Bá Ń Ronú Àtipa Ara Mi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àbí Kí N Para Mi Ni?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Mo Bá Ń Sorí Kọ́?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ṣé N Kúkú Para Mi?
    Jí!—2008
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 114
Ọ̀dọ́bìnrin kan tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ń wo bójò ṣe ń rọ̀ láti ojú wíńdò.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ayé Bá Sú Mi?

“Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn àníyàn gbà mí lọ́kàn gan-an, ṣe ló dà bí iná tí kò ṣeé pa. Láwọn àkókò yẹn ṣe ló ń ṣe mí bíi pé kí n pa ara mí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò fẹ́ kú. Ohun tí mo ṣáà fẹ́ ní pé kí gbogbo ìṣòro yìí dópin.”​—Jonathan ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17).

Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá (14,000), ìdá kan nínú márùn-ún ló sọ pé láàárín ọdún kan sẹ́yìn àwọn tí gbìyánjú láti pa ara àwọn.a Tí ayé bá sú ẹ, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi kó o pa ara ẹ, kí lo lè ṣe?

  • Ṣe sùúrù. Má ṣe kánjú ṣèpinnu tí ohun kan bá ń kó ẹ lọ́kàn sókè. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro náà lè ga bí òkè, fi sọ́kàn pé ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà.

Ọ̀dọ́bìnrin kan ń ronú ọ̀nà tó máa gbà yanjú ìṣòro rẹ̀.

Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà nǹkan lè má rí bó o ṣe rò. Kódà tó o bá rẹ́ni ràn ẹ́ lọ́wọ́, ojútùú ìṣòro náà lè má le tó bó o ṣe rò.

  • Ìlànà Bíbélì: “Wọ́n há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, àmọ́ kò le débi tí a ò fi lè yíra; ọkàn wa dà rú, àmọ́ kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbáyọ rárá.”​—2 Kọ́ríńtì 4:8.

    Àbá: Tó bá jẹ́ pé ó sábà máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o pa ara ẹ, ṣèwádìí bóyá ètò kan wà tí ìjọba ti ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ronú láti para wọn, tàbí kó o wá nọ́ńbà àwọn tó máa ń ṣe ìtọ́jú pàjáwìrì. Wọ́n ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, torí wọ́n ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè bójú tó irú ìṣòro bẹ́ẹ̀.

  • Bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọyì ẹ, tí wọ́n sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Lára wọn ni àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìdílé ẹ, àmọ́ tó ò bá sọ ìṣòro ẹ fún wọn, kò sí bí wọ́n ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Ọ̀dọ́bìnrin kan lo ìgò ojú.

Bó ṣe jẹ́ pé àwọn kan nílò ìgò ojú kí wọ́n lè ríran dáadáa. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rẹ́ gidi lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fojú tó tọ́ wo ìṣòro rẹ, kó o sì pinnu pé o ní pa ara rẹ.

  • Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ . . . jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

    Àbá: O lè sọ pé: “Ohun kan wà tí mò ń bá yí lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, mi ò mọ̀ bóyá mo lè bá yín sọ ọ́.” Tàbí kó o sọ pé: “Mo ní àwọn ìṣòro kan tí mi ò lè yanjú, ṣé ẹ lè ràn mí lọ́wọ́?”

  • Lọ rí dókítà. Àwọn àìsàn kan wà tó máa ń mú kéèyàn máa ṣàníyàn tàbí soríkọ́, ó sì lè mú kéèyàn máa ronú àtipa ara ẹ̀. Àmọ́ ìròyìn ayọ̀ kan ni pé àìsàn náà gbóògùn.

Ọ̀dọ́bìnrin kan tára rẹ̀ ò yá ń wò sùù, kò sì lè jẹ oúnjẹ tó wà níwájú rẹ̀.

Bó ṣe jẹ́ pé tí ara ẹnì kan ò bá yá, oúnjẹ ò ní wù ú jẹ, bákan náà téèyàn bá soríkọ́, ó lè máa ṣe é bíi kó para ẹ̀. Àmọ́, àwọn ìṣòro méjèèjì yìí ló gbóògùn.

  • Ìlànà Bíbélì: “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.”​—Mátíù 9:12.

    Àbá: Rí i pé ò ń sùn dáadáa, máa ṣe eré ìmárale, kó o sì máa jẹ oúnjẹ tó ṣaralóore. Torí pé to bá ní ìlera tó dáa, wàá lè ronú lọ́nà tó tọ́, ọkàn rẹ á sì balẹ̀.

  • Gbàdúrà. Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá wa “ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:20) O ò ṣe gbàdúrà sí i lónìí, kó o lo orúkọ ẹ̀ ìyẹn Jèhófà, kó o sì sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún un.

Ọ̀dọ́bìnrin kan gbìyànjú láti gbé ẹrù tó wúwo gan-an.

Àwọn ìṣòro kan wà tó nira láti dá yanjú. Àmọ́, Jèhófà Ẹlẹ́dàá rẹ ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  • Ìlànà Bíbélì: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín.”​—Fílípì 4:​6, 7.

    Àbá: Yàtọ̀ sí pé o sọ àwọn ìṣòro rẹ fún Jèhófà, gbìyànjú láti ronú lórí ó kéré tán ohun rere kan tí Jèhófà ṣe fún ẹ lónìí, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Kólósè 3:15) Tó o bá moore, ìyẹn a jẹ́ kó o túbọ̀ mọyì àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ẹ.

Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé ayé ti sú ẹ, jẹ́ kí ẹnì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ohun tí Jonathan tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Mo wá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kí n bá àwọn òbí mi sọ, kí n sì lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. Ọkàn mi ti balẹ̀ dáadáa báyìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì máa ń rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ kò ṣe mí bíi kí n pa ara mi mọ́.”

a Àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí sí bí wọ́n ṣe ń kápá àìsàn, tí wọ́n sì ń dènà ẹ̀ ní Amẹ́ríkà, ìyẹn Centers for Disease Control and Prevention ló ṣe ìwádìí yìí lọ́dún 2019.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Alexandra.

“Bí ìlera ara ti ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ ni ìlera ọpọlọ náà ṣe pàtàkì. Ìyàtọ̀ ibẹ̀ ni pé tí ẹnì kan bá kán lápá, gbogbo wa la máa rí i, àmọ́ tí ẹnì kan bá ní ẹ̀dùn ọkàn, kò sẹ́ni tó máa mọ̀. Tó o bá níṣòro, má bẹ̀rù láti sọ ọ́ fún ẹlòmíì. Kò sí ohun tó burú láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́.”​—Alexandra.

Ian.

“Láti kékeré làwọn òbí mi ti jẹ́ kí n mọ̀ pé kò sí ìṣòro kankan láyé yìí tí ò lè yanjú tàbí téèyàn ò lè fara dà. Ní tèmi, mo máa ń fọ̀rọ̀ lọ àwọn òbí mi, ìyẹn sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa fojú tó tọ́ wo àwọn ìṣòro mi.”​—Ian.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́

O ò ṣe kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá rẹ̀wẹ̀sì sílẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ kan rèé.

Sáàmù 34:18: “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọ̀rọ̀ àwọn tó níṣòro jẹ Jèhófà lógún gan-an. Ó wù ú kó ràn wọ́n lọ́wọ́.

Sáàmù 46:1: “Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa, ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Nígbàkigbà tí àníyàn bá gbà ẹ́ lọ́kàn, gbàdúrà sí Jèhófà. Ó ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dá àwọn ìṣòro ẹ.

Sáàmù 94:​18, 19: “Nígbà tí mo sọ pé: ‘Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀,’ Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ló ń gbé mi ró. Nígbà tí àníyàn bò mí mọ́lẹ̀, o tù mí nínú, o sì tù mí lára.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run máa fi Bíbélì ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù ẹ́ nínú lásìkò tó o nílò ìtùnú gan-an. Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ kan lọ láìka Bíbélì!

Sáàmù 139:​23, 24: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, . . . kí o sì mọ àwọn ohun tó ń gbé mi lọ́kàn sókè. Wò ó bóyá ìwà burúkú kankan wà nínú mi, kí o sì darí mi sí ọ̀nà ayérayé.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Jèhófà mọ̀ ẹ́ ju bó o ṣe mọ ara rẹ lọ. Ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí èrò tí kò dáa kó o lè láyọ̀.

Àìsáyà 41:10: “Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Ìṣòro yòówù ká máa kojú, Jèhófà máa fún wa lókun láti fara dà á.

Àtúnyẹ̀wò: Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ayé Bá Sú Mi?

  • Ṣe sùúrù. Ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe láti yanjú ìṣòro ẹ. Torí náà, pinnu pé o ò ní kánjú ṣe ohun tó bá wá sí ẹ lọ́kàn.

  • Bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Àwọn ìdílé àti ọ̀rẹ́ ẹ kò lè mọ ohun tó ò ń bá fínra àfi tó o bá sọ ìṣòro ẹ fún wọn.

  • Lọ rí dókítà. Ìrẹ̀wẹ̀sì lè jẹ́ kó máa ṣe èèyàn bíi pé kó pa ara ẹ̀, àmọ́ àìsàn tó gbóògùn ni.

  • Sọ bó ṣe rí lára ẹ fún Ọlọ́run nínú àdúrà. Ó mọ̀ ẹ́ ju bó o ṣe mọ ara ẹ lọ, ó sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́