ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 115
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Da Ẹ̀dùn Ọkàn Téèyàn Mi Bá Kú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Da Ẹ̀dùn Ọkàn Téèyàn Mi Bá Kú?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé ẹ̀dùn ọkàn mi ò ti máa pọ̀ jù báyìí?
  • Ohun tó o lè ṣe tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ bá pọ̀
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbé Pẹ̀lú Ẹ̀dùn-Ọkàn Mi?
    Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • Ohun Tó Lè Ran Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Lọ́wọ́
    Jí!—2018
  • Ó Ha Bójúmu Láti Nímọ̀lára Lọ́nà Yìí Bí?
    Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • Àwọn Nǹkan Tó Lè Ṣẹlẹ̀
    Jí!—2018
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 115
Ọmọbìnrin kan sùn sórí bẹ́ẹ̀dì, ó sì ń sunkún. Ó ń wo fọ́tò òun àti bàbá bàbá rẹ̀.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Da Ẹ̀dùn Ọkàn Téèyàn Mi Bá Kú?

Ṣé ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ kan kú láìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àdánù náà.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

  • Ṣé ẹ̀dùn ọkàn mi ò ti máa pọ̀ jù báyìí?

  • Ohun tó o lè ṣe tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ bá pọ̀

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Ṣé ẹ̀dùn ọkàn mi ò ti máa pọ̀ jù báyìí?

Ẹ̀dùn ọkàn táwọn kan máa ń ní tí èèyàn wọn bá kú máa ń pọ̀ gan-an.

“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti pé ọdún méjì tí bàbá mi àgbà ti kú, ọjọ́ kan ò lè lọ kí n máa rántí wọn. Gbogbo ìgbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀ nípa wọn ni mo máa ń sunkún.”​—Olivia.

“Ìyá mi àgbà máa ń fún mi níṣìírí kí ọwọ́ mi lè tẹ àwọn ohun tí mò ń lé, àmọ́ wọ́n kú kí ọwọ́ mi tó tẹ̀ ẹ́. Gbogbo ìgbà tí ọwọ́ mi bá tẹ ohun kan tí mò ń lé ni ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá mi torí ìyá mi àgbà tó ti kú.”​—Alison.

Bí kálukú ṣe máa ń ṣọ̀fọ̀ máa ń yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ:

“Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí ọkọ ẹ̀gbọ́n bàbá mi kú, ṣe ló dà bí àlá lójú mi. Ìgbà àkókó nìyẹn tí ẹni tó sún mọ́ mi máa kú, ṣe ló bá mi lójijì, ó sì dùn mí gan-an.”​—Nadine.

“Inú bí mi sí bàbá mi àgbà nígbà tí wọ́n kú torí pé wọn ò tọ́jú ara wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń tẹnu mọ́ ọn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.”​—Carlos.

“Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin nìkan ni mọ̀lẹ́bí tí kò sí níbẹ̀ nígbà tí bàbá wa àgbà kú. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara mi lẹ́bi pé mi ò sí níbẹ̀ nígbà tí wọ́n kú.”​—Adriana.

“Tọkọtìyàwọ́ kan tó sún mọ́ ìdílé wa kú nínú jàǹbá ọkọ̀. Lẹ́yìn ìgbà náà, ẹ̀rù máa ń bà mí tí ẹnì kan nínú ìdílé wa bá kúrò nílé, torí ó máa ń ṣe mí bíi pé òun náà máa kú.”​—Jared.

“Nígbà tí ìyá mi àgbà kú ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, mo kábàámọ̀ pé mi ò lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú wọn kí wọ́n tó ku.”​—Julianna.

Téèyàn wa bá kú, ó lè yà wá lẹ́nu, inú lè bí wa, a lè dá ara wa lẹ́bi, ẹ̀rù lè bà wá tàbí kó máa ṣe wá bí àbámọ̀. Kò sóhun tó burú tó bá ń ṣe wá bẹ́ẹ̀. Tọ́rọ̀ tiẹ̀ náà bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ẹ̀dùn ọkàn náà á máa dín kù. Ní báyìí ná, kí lo lè ṣe tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ bá pọ̀?

Ohun tó o lè ṣe tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ bá pọ̀

Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan. Bíbélì sọ pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ dà bí “ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.” (Òwe 17:17) Tó o bá sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún ẹnì kan, ìyẹn lè jẹ́ kára tù ẹ́.

“Kò sóhun tó burú téèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn ẹ̀ tó kú. Àmọ́, téèyàn bá ń bò ó mọ́ra, ẹ̀dùn ọkàn náà lè má tètè lọ. Ìdí nìyẹn tó fi dáa kéèyàn sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún ẹnì kan.”​—Yvette.

Máa rántí èèyàn ẹ tó kú. Bíbélì sọ pé “ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá.” (Lúùkù 6:45, Bíbélì Mímọ́) O lè kọ àwọn nǹkan rere tó o rántí nípa ẹni náà síbì kan tàbí kó o kó àwọn fọ́tò rẹ̀ jọ sínú ìwé kan.

“Mo kọ gbogbo àwọn nǹkan tí ọ̀rẹ́ mi kọ́ mi kó tó kú sílẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀ àwọn nǹkan tó ṣe ṣì ń ṣe mí láǹfààní. Bí mo ṣe kọ wọ́n sílẹ̀ ò jẹ́ kí n máa ṣàárò ẹ̀ jù.”​—Jeffrey.

Ọmọbìnrin kan ń kọ̀rọ̀ sínú ìwé.

Máa tọ́jú ara ẹ. Bíbélì sọ pé ó dáa kéèyàn máa ṣe eré ìmárale. (1 Tímótì 4:8) Rí i pé ò ń jẹ oúnjẹ tó ṣaralóore, ó ń ṣe eré ìmárale, ó sì ń sinmi dáadáa.

“Ìbànújẹ́ lè mú kéèyàn má lè ronú bó ṣe tọ́. Torí náà, o gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ò ń tọ́jú ara ẹ. Máa jẹun, kó o sì máa sùn dáadáa.”​—Maria.

Ọmọkùnrin kan ń ṣeré ìmárale.

Máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”​—Ìṣe 20:35.

“Máa ran àwọn míì lọ́wọ́, pàápàá àwọn tí èèyàn wọn náà ti kú. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọ̀ pé àwọn míì náà ní ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n ń bá yí.”​—Carlos.

Ọmọbìnrin kan ń ran ìyá àgbàlagbà kan lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe máa lo fóònù rẹ̀.

Máa sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ tó o bá ń gbàdúrà. Bíbélì pe Jèhófà Ọlọ́run ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Ó tún sọ pé Jèhófà “ń mú àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn lára dá; ó ń di àwọn egbò wọn.”​—Sáàmù 147:3.

“Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó sì fún ẹ lókun. Àwọn ìgbà kan máa wà tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ máa pọ̀ gan-an, àmọ́ fọkàn balẹ̀ torí pé Jèhófà kì í fi wá sílẹ̀.”​—Jeanette.

Má bọkàn jẹ́ tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ kò bá tètè lọ. Rántí pé bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe ń rí lára kálukú máa ń yàtọ̀ síra. Bíbélì sọ pé nígbà tí Jékọ́bù rò pé ọmọ òun ti kú, “kò gbà” kí àwọn míì tu òun nínú. (Jẹ́nẹ́sísì 37:35) Torí náà, má jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ ò bá tètè lọ.

“Oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń mú kí n rántí ẹ̀gbọ́n màmá màmá mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tí wọ́n ti kú.”​—Taylor.

Ká sọ pé ẹnì kan kán lẹ́sẹ̀. Kò sí àní-àní pé ìrora yẹn máa pọ̀, ó sì lè pẹ́ díẹ̀ kó tó jiná. Àmọ́, dókítà lè sọ àwọn ohun tẹ́nì náà lè ṣe táá jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ̀ tètè jiná.

Ọmọkùnrin kan tí wọ́n di ẹsẹ̀ rẹ̀ ń wo ẹni tó ń gun kẹ̀kẹ́ látojú wíńdò.

Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ náà nìyẹn tẹ́nì kan tó sún mọ́ wa bá kú. Ó máa ń dunni gan-an, ẹ̀dùn ọkàn náà sì lè gba àkókò díẹ̀ kó tó lọ. Torí náà, ṣe sùúrù. Ronú nípa àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, kó o sì ṣiṣẹ́ lórí àwọn èyí tó bá ipò rẹ mù jù lọ.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Isabelle.

“Ti pé ò ń sapá kí ẹ̀dùn ọkàn ẹ lè dín kù kò túmọ̀ sí pé o ò nífẹ̀ẹ́ èèyàn ẹ tó kú tàbí pé o fẹ́ gbàgbé ẹ̀. Ó dáa kó o máa rántí ohun tẹ́ni náà ti ṣe àti ipa tó ti kó nígbèésí ayé rẹ.”​—Isabelle.

Jordan.

“Má ṣe ronú pé ohun tó ò ń ṣe kò dáa torí pé ẹ̀dùn ọkàn ẹ ti ń lọ. Ti pé inú ẹ ti ń dùn pa dà kò túmọ̀ sí pé o kórìíra ẹni tó kú náà. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé o ti ń gbé ẹ̀dùn ọkàn náà kúrò lára, ó sì dájú pé ohun téèyàn ẹ tó kú náà máa fẹ́ fún ẹ nìyẹn ká sọ pé ó wà láàyè.”​—Jordan.

Àtúnyẹ̀wò: Báwo ni mo ṣe lè fara da ẹ̀dùn ọkàn téèyàn mi bá kú?

  • Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan. Tó o bá sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún ẹnì kan, ìyẹn lè jẹ́ kára tù ẹ́.

  • Máa rántí èèyàn ẹ tó kú. Máa rántí àwọn nǹkan dáadáa tẹ́ni náà ti ṣe, o tiẹ̀ lè kọ wọ́n sílẹ̀ pàápàá.

  • Máa tọ́jú ara ẹ. Máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, máa ṣe eré ìmáralé kó o sì máa sinmi dáadáa.

  • Máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Màá ran àwọn míì lọ́wọ́, pàápàá àwọn tí èèyàn wọn náà ti kú.

  • Máa sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ tó o bá ń gbàdúrà. Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó sì fún ẹ lókun.

  • Má bọkàn jẹ́ tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ kò bá tètè lọ. Rántí pé bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe ń rí lára kálukú máa ń yàtọ̀ síra.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́