ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 117
  • Àkóbá Wo Ni Ìkànnì Àjọlò Lè Ṣe fún Mi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àkóbá Wo Ni Ìkànnì Àjọlò Lè Ṣe fún Mi?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé mi kì í fi àkókò ṣòfò lórí ìkànnì àjọlò?
  • Ṣé ìkànnì àjọlò máa ń dí oorun mi lọ́wọ́?
  • Ṣé ìkànnì àjọlò lè ṣàkóbá fún bí nǹkan ṣe ń rí lára mi?
  • Àwọn Ọmọdé àti Ìkànnì Àjọlò—Apá 1: Ṣé Ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lo Ìkànnì Àjọlò?
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Kí N Má Lo Ìkànnì Àjọlò?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Ọmọdé àti Ìkànnì Àjọlò—Apá 2: Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Àwọn Elétò Ìlera Tó Jẹ́ Ọ̀gá Àgbà Kìlọ̀ Pé Ìkànnì Àjọlò Ń Ṣàkóbá Fáwọn Ọ̀dọ́​—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 117
Ọ̀dọ́bìnrin kan ń wo fóònù rẹ̀. Àwọn bèbí kéékèèké yí i ká.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Àkóbá Wo Ni Ìkànnì Àjọlò Lè Ṣe fún Mi?

Ṣé àwọn òbí rẹ fún ẹ láǹfààní láti lo ìkànnì àjọlò? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà mẹ́ta tó ṣe pàtàkì ní ìgbésí ayé rẹ.

Ní apá yìí

  • Ṣé mi kì í fi àkókò ṣòfò lórí ìkànnì àjọlò?

  • Ṣé ìkànnì àjọlò máa ń dí oorun mi lọ́wọ́?

  • Ṣé ìkànnì àjọlò lè ṣàkóbá fún bí nǹkan ṣe ń rí lára mi?

  • Ohun tí àwọn ojúgbà ẹ sọ

Ṣé mi kì í fi àkókò ṣòfò lórí ìkànnì àjọlò?

Ṣe ni ìkànnì àjọlò dà bí ìgbà tèèyàn gun ẹṣin tí kò ní ìjánu, ṣé wà á gbà kó gbé ẹ ṣubú, àbí wà á fi ìjánu dá a dúró.

“Nígbà tí mo bá fẹ́ lo ìkànnì àjọlò fún ìṣẹ́jú díẹ̀, kí n tó mọ̀ wákàtí mélòó kan ti lọ! Mo wá rí i pé ìkànnì àjọlò lè di bárakú ó sì ń fi àkókò ẹni ṣòfò.”​—Joanna.

Ǹjẹ́ o mọ̀? Àwọn tó ṣe ìkànnì àjọlò mọ̀ pé bí àwọn tó ń lò ó bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni owó tí wọ́n máa rí á ṣe pọ̀ torí àwọn tó ń polówó ọjà. Èyí ló mú kí ìkànnì àjọlò di bárakú.

Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé kì í ṣe pé mo kàn ń fi àkókò mi ṣòfò bí mo ṣe ń lọ sórí ìkànnì àjọlò láìnídìí? Ṣé mo lè lo lára àkókò náà láti fi ṣe àwọn nǹkan míì tó nítumọ̀?’

Ohun tó o lè ṣe. Pinnu iye àkókò tó o máa lò lórí ìkànnì àjọlò, kó o sì dúró lórí ìpinnu rẹ.

Ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ọ̀dọ́kùnrin kan ń ṣe. 1. Ó wà lórí bẹ́ẹ̀dì, ó gbé ẹ̀rọ tó ń gbóhùn jáde sétí, ó sì ń tẹ fóònù. 2. Òun àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń gbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀.

Pinnu iye àkókò tó o máa lò lórí ìkànnì àjọlò

“Mo ṣe ètò kan sórí fóònù mi tó fi jẹ́ pé tí iye àkókò tí mo pinnu láti lò lórí ìkànnì àjọlò bá ti pé, ó máa kú fúnra ẹ̀. Ohun tí mo ṣe yìí ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti mọ bí màá ṣe lo ìkànnì àjọlò, kí n má sì fi àkókò ṣòfò.”​—Tina.

Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”​—Éfésù 5:16.

Ṣé ìkànnì àjọlò máa ń dí oorun mi lọ́wọ́?

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé ó kéré tán, ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa sun oorun wákàtí mẹ́jọ lálẹ́, àmọ́ ọ̀pọ̀ wọn ni kì í sùn tó bẹ́ẹ̀. Ìkànnì àjọlò sì wà lára ohun tó máa ń fà á.

“Mo máa ń tẹ fóònù kí n tó lọ sùn. Kí n tó mọ̀, mo ti lo ọ̀pọ̀ wákàtí níbi tí mo ti ń wo ohun táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì àjọlò. Mo mọ̀ pé ìwà tí ò dáa ni, ó sì yẹ kí n jáwọ́ níbẹ̀.”​—Maria.

Ǹjẹ́ o mọ̀? Téèyàn ò bá sùn dáadáa, ìyẹn lè mú kéèyàn máa ṣàníyàn, kó sì máa rẹ̀wẹ̀sì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Jean Twenge tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìrònú ẹ̀dá sọ pé, téèyàn ò bá sùn dáadáa, ara ẹ̀ ò ní yá gágá, inú ẹ̀ ò sì ní dùn. Ó fi kún un pé, “tó bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀,” ìrònú ẹni náà lè má já geere mọ́, kó sì yọrí sí “àìsàn ọpọlọ tó burú.”a

Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń sùn tó bó ṣe yẹ?’ ‘Àbí ṣe ni mo máa ń wo ìkànnì àjọlò lásìkò tó yẹ kí n lọ sùn?’

Ohun tó o lè ṣe. Tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí fóònù rẹ jìnnà sí ẹ tó o bá fẹ́ lọ sùn. Tó bá tiẹ̀ ṣeé ṣe, wákàtí méjì kó o tó lọ sùn ni kó o ti gbé fóònù ẹ̀ sílẹ̀. Tó o bá fẹ́ kí àláàmù jí ẹ láàárọ̀, o lè lo èyí tí kò sí lórí fóònù tàbí tablet rẹ.

Ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ọ̀dọ́bìnrin kan ń ṣe láàárọ̀. 1. Ó jókòó sórí bẹ́ẹ̀dì, kò fẹ́ dìde. 2. Ó jókòó sórí bẹ́ẹ̀dì, inú ẹ̀ sì ń dùn bó ṣe ń nara.

Kó o tó lọ sùn ni kó o ti gbé fóònù ẹ sílẹ̀

“Nígbà míì, mo máa ń pẹ́ lọ sùn torí pé mò ń tẹ fóònù, àmọ́ mo ti ń ṣiṣẹ́ lé e lórí. Ó yẹ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà àgbà káwọn èèyàn lè fọkàn tán mi. Mo gbọ́dọ̀ tètè máa sùn kára mi lè yá gágá lọ́jọ́ kejì.”​—Jeremy.

Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:10.

Ṣé ìkànnì àjọlò lè ṣàkóbá fún bí nǹkan ṣe ń rí lára mi?

Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe, ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì àwọn ọmọbìnrin tó wà nílé ẹ̀kọ́ ló sọ pé, “ọ̀pọ̀ ìgbà ni inú àwọn kì í dùn, ó sì máa ń ṣe àwọn bíi pé ó ti tán fáwọn.” Ó ṣeé ṣe kí ìkànnì àjọlò wà lára ohun tó fà á. Dókítà Leonard Sax sọ pé: “Bó o bá ṣe ń lo àkókò sí i lórí ìkànnì àjọlò, tó ò ń fi ara ẹ wé àwọn míì, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa rẹ̀wẹ̀sì.”b

“Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń fi ara wọn wé àwọn míì, ìkànnì àjọlò sì máa ń mú kó rọrùn fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń wo ohun táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì àjọlò, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ìgbésí ayé wọn sàn ju tìẹ lọ. Tó o bá sì ń wo ohun táwọn ọ̀rẹ́ ẹ gbé síbẹ̀, níbi tí wọ́n ti ń ṣe fàájì tàbí tí wọ́n ti ń jayé, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé wọ́n ń gbádùn jù ẹ́ lọ.”​—Phoebe.

Ǹjẹ́ o mọ̀? Òótọ́ ni pé ìkànnì àjọlò lè mú kíwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ máa kàn sí ara yín, àmọ́ kò lè dà bíi pé kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ lójúkojú. Dókítà Nicholas Kardaras sọ pé: “Bínú wa ṣe máa ń dùn tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ yàtọ̀ sí bínú wa ṣe máa ń dùn tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Kódà àwọn èèyàn máa ń sọ pé ojú lọ̀rọ̀ wà.”c

Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dá wà tí mo bá ń wo ohun táwọn ọ̀rẹ́ mi ń ṣe?’ ‘Ṣé ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò gbádùn ayé mi tí mo bá ń rí oríṣiríṣi nǹkan táwọn ọ̀rẹ́ mi ń gbé sórí ìkànnì àjọlò tó mú kó dà bíi pé wọ́n ń gbádùn ayé wọn?’ ‘Ṣé mi ò kì í rẹ̀wẹ̀sì tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló tẹ àmì pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí mo gbé sórí ìkànnì àjọlò?’

Ohun tó o lè ṣe. O lè pinnu pé o ò ní lo ìkànnì àjọlò fún ọjọ́ mélòó kan, ọ̀sẹ̀ kan tàbí oṣù kan pàápàá. Kó o wá túbọ̀ máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lójúkojú tàbí kó o máa pè wọ́n lórí fóònù. Ó ṣeé ṣe kó o rí i pé ara á tù ẹ́, wàá sì túbọ̀ láyọ̀ ní gbogbo ìgbà tí o kò bá lo ìkànnì àjọlò.

Ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ọ̀dọ́bìnrin kan ń ṣe. 1. Inú ẹ kò dùn bó ṣe ń wo fọ́tò àwọn míì lórí fóònù rẹ̀. 2. Òun àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ń mu áásìkiriìmù, inú ẹ̀ sì ń dùn bí wọ́n ṣe jọ ń sọ̀rọ̀ níta.

Ṣé o lè túbọ̀ máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lójúkojú?

“Mo kíyè sí i pé tí mo bá ń lo ìkànnì àjọlò, ohun táwọn míì ń ṣe ló máa ń gbà mí lọ́kàn. Mo wá pinnu pé mi ò ní lo ìkànnì àjọlò mọ́, mo sì yọ ọ́ kúrò lórí fóònù mi. Lẹ́yìn tí mo ṣe bẹ́ẹ̀, ara tù mí, ọkàn mi sì balẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ ráyè fáwọn nǹkan pàtàkì míì.”​—Briana.

Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.”​—Gálátíà 6:4.

a Látinú ìwé iGen.

b Látinú ìwé Why Gender Matters.

c Látinú ìwé Glow Kids.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Phoebe.

“Ọ̀pọ̀ àkókò ni mo fi ń ṣòfò lórí ìkànnì àjọlò, mi ò sì láyọ̀. Mo wá pinnu pé mi ò ní lò ó mọ́. Nígbà tó yá, mi ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n lára pé mi ò lò ó mọ́. Ní báyìí, ọkàn mi balẹ̀, inú mi ń dùn, mo sì ráyè fáwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé.”​—Phoebe.

Jacob.

“Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń yọ ìkànnì àjọlò kúrò lórí fóònù mi. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n lè ronú lórí àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì, kí n sì ráyè ṣe wọ́n. Ọ̀pọ̀ nǹkan pàtàkì míì ni mo lè fàkókò mi ṣe dípò kí n kàn máa wo ìkànnì àjọlò lórí fóònù.”​—Jacob.

Sienna.

“Mo ṣì lè pinnu láti lo ìkànnì àjọlò lọ́jọ́ iwájú o, àmọ́ ní báyìí ná, mi ò lò ó mọ́. Mo fẹ́ rí i dájú pé àwọn nǹkan pàtàkì tó kan ìgbésí ayé mi ni mò ń ṣe, dípò kí n máa ronú ṣáá nípa ohun táwọn míì ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe. Ìkànnì àjọlò lè mú kéèyàn gbàgbé àfojúsùn ẹ̀ títí kan àwọn ọ̀rẹ́ gidi téèyàn ní.”​—Sienna.

Àtúnyẹ̀wò: Àkóbá wo ni ìkànnì àjọlò lè ṣe fún mi?

  • Ṣé kì í fàkókò mi ṣòfò? Pinnu iye àkókò tó o máa lò lórí ìkànnì àjọlò, kó o sì dúró lórí ìpinnu rẹ.

  • Ṣé kì í dí oorun mi lọ́wọ́? Wákàtí méjì kó o tó lọ sùn ni kó o ti gbé fóònù ẹ sílẹ̀.

  • Àkóbá wo ló lè ṣe fún bí nǹkan ṣe ń rí lára mi? Pinnu pé o ò ní lo ìkànnì àjọlò fáwọn àkókò kan, kó o wá túbọ̀ máa wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lójúkojú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́