ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 57
  • Àǹfààní Tí Ikú Jésù Ṣe Wá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àǹfààní Tí Ikú Jésù Ṣe Wá
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
  • Ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì àti fídíò
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ohun Tí Lílọ sí Ìpàdé Ń Sọ Nípa Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fi Fídíò Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Ta Ni Jésù?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 57
Jésù gbé òpó igi tí wọ́n fẹ́ kàn án mọ́.

Àǹfààní Tí Ikú Jésù Ṣe Wá

Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀pọ̀ àwọn tó bá dara pọ̀ mọ́ wa kárí ayé máa ń ṣe Ìrántí Ikú Jésù bó ṣe pa á láṣẹ. (Lúùkù 22:19) Bá a ṣe ń wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí fi hàn pé a mọrírì ohun ribiribi tí Jésù ṣe bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún aráyé. Bákan náà, ó máa jẹ́ ká mọ àǹfààní tí ikú Jésù lè ṣe wá ní báyìí àti ní ọjọ́ iwájú.​—Jòhánù 3:16.

Kí la lè ṣe ká lè jàǹfààní nínú ikú ìrúbọ Jésù, bóyá a wá síbi ìrántí ikú rẹ̀ àbí a ò ṣe bẹ́ẹ̀? Jésù jẹ́ ká mọ ohun méjì tá a lè ṣe.

  1. 1. Kẹ́kọ́ọ̀ nípa Ọlórun àti Jésù. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.”​—Jòhánù 17:3.

  2. 2. Fi ohun tí ò ń kọ́ sílò. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká fi ohun tí à ń kọ́ sílò láyé wa. Bí àpẹẹrẹ, bí Jésù ṣe ń parí Ìwàásù Orí Òkè, ó gbóríyìn fún gbogbo ẹni “tó ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ [rẹ̀], tó sì ń ṣe é.” (Lúùkù 6:46-48) Ó tún sọ níbòmíì pé: “Tí ẹ bá mọ àwọn nǹkan yìí, aláyọ̀ ni yín tí ẹ bá ń ṣe wọ́n.”​—Jòhánù 13:17.

Ṣé wàá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run àti Jésù? Ṣé wàá fẹ́ mọ bó o ṣe lè fi ohun tí ò ń kọ́ sílò? Wo àwọn ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti lóye ohun tó wà nínú Bíbélì, wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò láyé wọn.

  • Lọ sí abala Ẹnì Kan Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

  • Wo fídíò náà Ohun Tó O Máa Gbádùn Nínú Ẹ̀kọ́ Bíbélì Rẹ kó o lè mọ bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ìpàdé lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ní àwọn ilé ìpàdé wa. Láwọn ìpàdé yìí, a máa ń jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì àti bá a ṣe lè fi wọ́n sílò nígbèésí ayé wa.

Gbogbo èèyàn ló lè wá sáwọn ìpàdé yìí títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá fẹ́, o lè dara pọ̀ mọ́ wọn lójúkojú tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

  • Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó o máa gbádùn láwọn ìpàdé wa, wo fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?

  • Tó o bá fẹ́ mọ ibi tá a ti ń ṣèpàdé tó sún mọ́ ẹ, lọ sí abala Ìpàdé Ìjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì àti fídíò

Ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ àti fídíò tó wà lórí ìkànnì yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ sí i nípa àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti bí ikú rẹ̀ ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní.

Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ mọ bí ikú ọkùnrin kan ṣe lè ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní, ka àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Jésù Ṣe Ń Gbani Là?” àti “Kí Nìdí Tí Jésù Fi Jìyà Tó sì Kú?” tàbí kó o wo fídíò náà Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́