Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Ń Bójú Tó Àwọn Adití?
Àwọn adití tó wà kárí ayé báyìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́rin (70) mílíọ̀nù, oríṣiríṣi èdè adití tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì (200) ni wọ́n sì fi ń sọ̀rọ̀. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé àwọn èèyàn sábà máa ń hùwà àìdáa sáwọn adití yìí. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun táwọn kan sọ:
“Kárí ayé làwọn èèyàn ti ń fi ẹ̀tọ́ àwọn adití àtàwọn tí ò gbọ́ràn dáadáa dù wọ́n.”—Ẹgbẹ́ Àwọn Adití Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
“Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, àwọn adití máa ń wà lára àwọn tálákà tíyà ń jẹ jù. Wọn kì í sábà láǹfààní láti lọ sílé ẹ̀kọ́, kí wọ́n ríṣẹ́ táá máa mówó wọlé fún wọn, ọ̀pọ̀ nǹkan tó sì yẹ kí wọ́n mọ̀ ni wọn ò mọ̀.”—Àjọ Àwọn Adití Àgbáyé.
Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ ka ọ̀rọ̀ àwọn adití sí? Kí ni Bíbélì sọ nípa àwọn adití? Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lóde òní?
Bí Ọ̀rọ̀ Àwọn Adití Ṣe Rí Lára Ọlọ́run
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófàa Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn adití, ó sì kà wọ́n sí. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa rẹ́ wọn jẹ, ó sì fẹ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tó máa ṣe wọ́n láǹfààní.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣépè fún adití.”—Léfítíkù 19:14.
Ohun tó túmọ̀ sí: Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ò fàyè gbà á kí wọ́n hùwà àìdáa sáwọn adití.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.”—Ìṣe 10:34.
Ohun tó túmọ̀ sí: Gbogbo èèyàn ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́, títí kan àwọn adití, láìka ibi tí wọ́n ti wá, àṣà ìbílẹ̀ wọn àti èdè tí wọ́n ń sọ sí.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Jésù . . . bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri . . . , ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà.”—Mátíù 9:35.
Ohun tó túmọ̀ sí: Jésù wá sáyé láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tí ìjọba yẹn máa ṣe fún gbogbo èèyàn, títí kan àwọn tó jẹ́ adití.—Mátíù 6:10.
Ohun tí Bíbélì sọ: Jésù mú kí “àwọn adití gbọ́ràn, kí àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ sì sọ̀rọ̀.”—Máàkù 7:37.
Ohun tó túmọ̀ sí: Jésù ṣe àwọn ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé nínú Ìjọba Ọlọ́run, àwọn adití máa gbọ́rọ̀, àwọn tí kò lè sọ̀rọ̀ á sì sọ̀rọ̀. Nígbà tó fẹ́ wo ọkùnrin adití kan sàn, ó fara ṣàpèjúwe fún ọkùnrin náà kó tó wò ó sàn.—Máàkù 7:31-35.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Etí àwọn adití . . . máa ṣí.”—Àìsáyà 35:5.
Ohun tó túmọ̀ sí: Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí etí àwọn adití máa là.—Àìsáyà 29:18.
Báwo Làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ń Ran Àwọn Adití Lọ́wọ́ Lóde Òní?
Kárí ayé làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn adití. Báwo la ṣe ń ṣe é? À ń ṣe Bíbélì àtàwọn fídíò míì tó ń ṣàlàyé Bíbélì jáde ní èdè adití tó ju ọgọ́rùn-ún kan (100) lọ. Yàtọ̀ síyẹn, à ń kọ́ àwọn adití lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a sì tún máa ń pé jọ láwọn Ilé Ìpàdé wa láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lédè àwọn adití. A kì í gba owó kankan fáwọn ohun tá à ń ṣe yìí. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Torí àṣẹ tí Jésù pa ni. Ó sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:8.
Wàá rí àwọn fídíò tá a fi ń kọ́ àwọn adití lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì wa. O lè fi dátà wò ó tààràtà tàbí kó o wà á jáde sórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà ẹ. Lọ sí:
JW.ORG. Wàá rí àmì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yìí lókè pátápátá ní abala èyíkéyìí tó o bá wà lórí ìkànnì jw.org. Tẹ̀ ẹ́, kó o lè wá èdè adití tó o fẹ́.
JW Library Sign Language app. Ọ̀fẹ́ ni. Tó o bá wà á jáde sórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà ẹ, wàá rí àwọn fídíò èdè adití níbẹ̀. O lè wa àwọn fídíò náà jáde tàbí kó o fi dátà wò ó tààràtà.
Kí Làwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Bíbélì ní èdè adití. Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè àwọn adití ti Amẹ́ríkà ni Bíbélì àkọ́kọ́ tó wà lódindi lédè àwọn adití kárí ayé. Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti wà báyìí lódindi tàbí lápá kan ní ọ̀pọ̀ èdè adití, ọdọọdún ni iye àwọn èdè yẹn sì ń pọ̀ sí i. (Tó o bá fẹ́ mọ àwọn Bíbélì tó ti wà lédè adití tàbí tó o fẹ́ wo fídíò Bíbélì lórí ìkànnì, wo àpótí tá a pè ní “Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Lédè Àwọn Adití.”)
Wo fídíò tá a pe àkòrí ẹ̀ ní A Ti Wá Ní Odindi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Lédè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà kó o lè mọ iṣẹ́ tá à ń ṣe ká tó mú Bíbélì jáde lédè adití.
Tó o bá fẹ́ túbọ̀ gbádùn Bíbélì kíkà, wa JW Library Sign Language app jáde sórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà ẹ. Ó máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti wo fídíò àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtó lédè adití.
Adití ni Dmytro àti Vita, àmọ́ àwọn ọmọ wọn kì í ṣe adití. Wo àǹfààní tí ìdílé wọn rí bí wọ́n ṣe ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ lédè adití.
Àwọn fídíò tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe oríṣiríṣi fídíò jáde lédè àwọn adití tó ń jẹ́ káwọn èèyàn rí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì tó máa ń tún ayé ẹni ṣe. Àwọn fídíò yìí wà fáwọn . . .
Ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O lè ní kí ẹnì kan wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè adití tó o gbọ́ lásìkò tó rọrùn fún ẹ. Gbìyànjú ẹ̀ wò tó bá wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.
Orílẹ̀-èdè Philippines ni Jeson Senajonon ń gbé. Wo bí ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ àwọn èèyàn ṣe jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.
Pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ni Mario Antúnez lórílẹ̀-èdè Honduras. Ka ìtàn ìgbésí ayé ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Ohun Tí Ò Yé Mi Pọ̀ Ju Èyí Tó Yé Mi Lọ” kó o lè mọ bó ṣe rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó wà lọ́kàn ẹ̀ nínú Bíbélì.
Àwọn ìpàdé wa. Kárí ayé la ti láwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ tó ń sọ èdè àwọn adití, àwọn tó jẹ́ adití sì máa ń wá síbẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń ṣètò àwọn àpéjọ ńlá tá a ti máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè adití lọ́dọọdún. Láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ yìí, ètò wà láti fọwọ́ ṣàpèjúwe lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fáwọn adití tí kò lè ríran. A tún máa ń tẹ ìwé àwọn afọ́jú jáde lọ́fẹ̀ẹ́ fáwọn tí ò ríran.
Wá ìjọ tó sún mọ́ ẹ.
Wo ìsọfúnni nípa àwọn àpéjọ wa ọdọọdún.
Lọ sí ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù tá a máa ń ṣe lọ́dún, ìyẹn Ìrántí Ikú Jésù.
Orílẹ̀-èdè Mexico ni José Luis Ayala ń gbé. Adití ni wọ́n bí i, ó sì tún wá fọ́jú nígbà tó yá. Wo ohun tó sọ ọ́ di ẹni tó ń kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó já fáfá.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ yìí, “Ta ni Jèhófà?”