Chris McGrath/Getty Images
Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Ogun
Ogun tó ń jà kárí ayé ti ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́, ó sì ti fa ọ̀pọ̀ ìnira fáwọn èèyàn. Kíyè sí àwọn ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí:
- “Iye àwọn tí ogun pa lórílẹ̀-èdè Etiópíà àti Ukraine lọ́dún tó kọjá nìkan ju àwọn tí ogun ti pa láti ọdún 1994.”—Peace Research Institute Oslo, June 7, 2023. 
- “Lọ́dún 2022, ogun tó jà ní Ukraine wà lára ogun tó tíì burú jù lọ. Kárí ayé ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn olóṣèlú légbá kan sí i lọ́dún tó kọjá, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lèyí sì ṣàkóbá fún.”—The Armed Conflict Location & Event Data Project (ACLED), February 8, 2023. 
Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀. Ó sọ pé “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ Ìjọba yìí, Ọlọ́run máa “fòpin sí ogun kárí ayé.”—Sáàmù 46:9.