Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ohun Táá Jẹ́ Kó O Láyọ̀ Lákòókò Tí Nǹkan Le Yìí—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Lásìkò tá a wà yìí, kò sẹ́ni tó lè sọ bí nǹkan ṣe máa rí tàbí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sóun. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ lè kóni lọ́kàn sókè, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé ojú tá a bá fi ń wo nǹkan ló máa pinnu bóyá a máa láyọ̀, kì í ṣe ipò tá a bá ara wa. Bíbélì sọ pé “ojoojumọ ni ọdún fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn” láìka ìṣòro tó ní sí. (Òwe 15:15, Yoruba Bible) Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ kí inú wa máa dùn? Ẹ jẹ́ ká wo ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún wa.
Ohun tó o lè ṣe tó o bá ń ṣàníyàn
Bíbélì sọ pé: “Àníyàn inú ọkàn máa ń mú kó rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ ọ̀rọ̀ rere máa ń mú kó túra ká.”—Òwe 12:25.
Àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè gbé àníyàn kúrò lọ́kàn. Tó o bá fẹ́ mọ̀ ọ́, ka àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àníyàn.”
Ohun tó o lè ṣe tó o bá dá wà
Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”—Òwe 17:17.
Bíbélì sọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe kó o lè ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi táá dúró tì ẹ́, ìyẹn ni ò sì ní jẹ́ kó o máa dá wà. Ka àpilẹ̀kọ náà “Tó O Bá Láwọn Ọ̀rẹ́, O Lè Borí Ìṣòro Ìdánìkanwà—Bí Bíbélì Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́.”
Bó o ṣe lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò ẹ
Bíbélì sọ pé: “Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. . . . Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”a—Mátíù 22:37-39.
Tá a bá ń gbàdúrà, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Ọlọ́run Ń Gbọ́ Àdúrà Wa?”
A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tá a bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Bíbélì táwọn èèyàn máa ń pè ní Òfin Oníwúrà. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Òfin Oníwúrà?”
O ò ṣe wo àwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ láyọ̀ lákòókò tí nǹkan le yìí. A rọ̀ ẹ́ pé kó o gbìyànjú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń ṣe fáwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.