ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Jẹ Oúnjẹ Tó Ṣara Lóore?
Ìwọ náà mọ̀ pé oúnjẹ tí kò ṣara lóore máa ń ṣàkóbá fún ìlera èèyàn. Àwọn tí oúnjẹ tí kò ṣara lóore bá mọ́ lára nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́ máa ń bá a lọ títí wọ́n á fi dàgbà, torí náà, àti ìsìnyí ni kó o ti jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore.
Irú oúnjẹ wo ló ń ṣara lóore?
Bíbélì sọ fún wa pé ká “má ṣe jẹ́ aláṣejù,” èyí sì kan bí a ṣe ń jẹun. (1 Tímótì 3:11) Tá a bá fi ìlànà Bíbélì yìí sọ́kàn, a máa rí i pé . . .
- Oríṣiríṣi oúnjẹ ló máa ń ṣara lóore. Irú bíi wàrà, bọ́tà tàbí àwọn oúnjẹ tó ní èròjà purotéènì, èso, ewébẹ̀ àti oríṣiríṣi ọkà. Ọ̀pọ̀ èèyàn kì í jẹ àwọn oúnjẹ yìí torí wọ́n rò pé ó máa mú káwọn sanra. Ṣùgbọ́n, téèyàn ò bá jẹ àwọn oúnjẹ yìí, ó lè ṣàkóbá fún ara ẹ̀. - Gbìyànjú ẹ̀ wò: Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa àwọn oúnjẹ tó ní èròjà tó ń ṣara lóore, wádìí tàbí kó o lọ rí dọ́kítà rẹ. Bí àpẹẹrẹ: - Èròjà Carbohydrate máa ń fún ara lókun. Èròjà purotéènì máa ń dènà àrùn, ó sì máa ń jẹ́ káwọn sẹ́ẹ̀lì ara wa ṣiṣẹ́ dáadáa. Tí ọ̀rá kò bá pọ̀ jù lára, ó máa ń dènà àrùn ọkàn, èyí á sì jẹ́ kára wa dá ṣáṣá. - “Mo máa ń gbìyànjú láti jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore. Mi ò rò pé ó burú téèyàn bá ń jẹ nǹkan dídùn bíi súìtì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, á dáa ká máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore. Ká sì máa wà ní ìwọ̀ntún-wọ̀nsì.”—Brenda. - Tí óunjẹ ò bá ní àwọn èròjà tó dáa nínú, ó dà bí àga tí ẹsẹ̀ ẹ̀ kan ti kán 
- Oúnjẹ tó ṣara lóore kì í ṣàkóbá fún ara. Téèyàn ò bá jẹun kánú tàbí tí kò jẹun nígbà tó yẹ, tó wá jẹ oúnjẹ púpọ̀ nígbà tí ebi ń pa á tàbí téèyàn ò bá kìí jẹ nǹkan tó fẹ́ràn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè ṣàkóbá fún ara. - Gbìyànjú ẹ̀ wò: Kíyè sí oúnjẹ tó ò ń jẹ fún odindi oṣù kan. Ìgbà mélòó lo jẹ oúnjẹ tí kò ṣara lóore? Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore? - “Tẹ́lẹ̀, ó lásìkò tí mo máa ń jẹ ounjẹ tó lè mú kéèyàn sanra àti ìgbà tí mo máa ń jẹ oúnjẹ tí kì í mú kéèyàn sanra. Àmọ́ nígbà tó yá, mi ò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, mo wá pinnu pé mi ò ní jẹ àjẹjù, mi ò sì ní jẹun tí mo bá ti yó. Ó ṣe díẹ̀ kó tó mọ́ mi lára, àmọ́ ní báyìí, mo ti ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore.”—Hailey 
Báwo ni mo ṣe lè máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore déédéé?
- Ronú ṣáájú. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.” (Òwe 21:5) Tó o bá fẹ́ máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, ronú nípa ẹ̀ dáadáa. - “Ó máa ń gba ìsapá kéèyàn tó lè jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, àmọ́ oúnjẹ tá a bá sè nílé ló dáa jù. Kò rọrùn ṣùgbọ́n ó máa ṣe wá láǹfààní, ó tún máa jẹ́ ká ṣọ́wó ná.”—Thomas 
- Pinnu oúnjẹ tó ṣara lóore tí wàá máa jẹ. Bíbélì sọ pe: “Má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ . . . bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.” (Òwe 3:21) Ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa kó o lè mọ àwọn oúnjẹ tó ṣara lóore tí wàá máa jẹ. - “Lójoojúmọ́, mo máa ń fi oúnjẹ tó ṣara lóore rọ́pò èyí tí kò ṣara lóore. Bí àpẹẹrẹ, dípò kí n jẹ súìtì, mo máa ń jẹ ápù. Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore!”—Kia. 
- Ní àfojúsùn tó bọ́gbọ́n mu. Bíbélì sọ pé: “Máa fi ayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ.” (Oníwàásù 9:7) Ti pé ò ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore ò túmọ̀ sí pé o ò ní lè jẹ àwọn oúnjẹ tó o fẹ́ràn tàbí kó o máa dààmú ní gbogbo ìgbà tó o bá fẹ́ jẹun. Tó ò bá tiẹ̀ fẹ́ sanra, rántí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bó o ṣe máa ní ìlera tó dáa. Ní àfojúsùn tó bọ́gbọ́n mu nípa oúnjẹ tó ṣara lóore. - “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo sapá láti dín bí mo ṣe sanra kù, àmọ́ ní gbogbo ìgbà yẹn, mi ò fi ebi pa ara mi, mi ò sá fún àwọn oúnjẹ kan tàbí kí n bínú síra mi torí pé mo jẹ súìtì. Mo mọ̀ pé ó máa gba ìsapá tí mi ò bá fẹ́ sanra jù àmọ́ ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”—Melanie.