Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Tó o bá ronú pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan tó o ti dá ní kò jẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà rẹ, ńṣe ni kó o fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn òbí rẹ létí. Kó o tún lọ bá “àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ [fún ìrànlọ́wọ́].” (Jákọ́bù 5:14) Àwọn alàgbà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tún pa dà ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.