Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Bíi tọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni olóòótọ́ kan lónìí náà rí towó ṣe. Àmọ́, Ọlọ́run kìlọ̀ fún wọn pé wọ́n ò gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ tí wọ́n ní, wọn ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kó gbà wọ́n lọ́kàn. (Òwe 11:28; Máàkù 10:25; Ìṣípayá 3:17) Yálà a lówó lọ́wọ́ ni o tàbí a kò ní, ká sáà ti rí i pé ìfẹ́ Ọlọ́run là ń ṣe nígbà gbogbo.—Lúùkù 12:31.