Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Tún kíyè sí pé, ó níbi tí àṣẹ ọkùnrin mọ nínú ìjọ. Ó wà lábẹ́ àṣẹ Kristi, ó sì gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ó tún ṣe pàtàkì pé kí àwọn tó wà nípò àbójútó nínú ìjọ “wà ní ìtẹríba fún ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìbẹ̀rù Kristi,” kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀.—Éfésù 5:21.