Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Awọn kan dábàá idi miiran: Ó ṣeeṣe ki imọ-ọran Greek ti ní ipa lori awọn Jew. Fun apẹẹrẹ, Philo, olumọran Jew kan ní Alexandria tí ó fẹrẹẹ jẹ ojúgbà kan naa pẹlu Jesu, jẹ ẹni tí olumọran Greek naa Plato ní ipa lori rẹ̀ gidigidi, ẹni tí oun rò pè ó wà labẹ imisi atọrunwa. Lexikon des Judentums [Iwe-aṣọ̀rọ̀jọ-fun-itumọ Ẹkọ-isin Jew] labẹ “Philo,” sọ pe Philo ṣe isopọṣọkan ede ati awọn ero imọ-ọran Greek (Plato) pẹlu igbagbọ awọn Jew tí a gbagbọ pe a kọ́ araye ní taarata lati ọwọ Ọlọrun” ati pe lati ibẹrẹ ni oun ti ní “ipa tí ó ṣee fojuri lori awọn baba ṣọọṣi Kristian.” Philo kọnilẹkọọ pe Ọlọrun jẹ alaile ṣee tumọ ati pe, fun idi yii, ó jẹ alaile ṣee pè lorukọ.