Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìforúkọsílẹ̀ yìí mú kí ó túbọ̀ ṣeé ṣe fún Ilẹ̀-Ọba Romu láti fọ̀ranyàn béèrè owó orí. Nítorí ìdí èyí, láìmọ̀ tẹ́lẹ̀ ni Augustu ṣèrànwọ́ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa alákòóso kan tí yóò mú “agbowóòde kan rékọjá nínú ògo ìjọba” ṣẹ. Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà yẹn sọtẹ́lẹ̀ pé “ọmọ-aládé májẹ̀mú,” tàbí Messia, ni a óò ‘fọ́ túútúú’ ní ọjọ́ ẹni tí yóò gbapò alákòóso yìí. Wọ́n pa Jesu lákòókò ìṣàkóso Tiberiu, ẹni tí ó gbapò Augustu.—Danieli 11:20-22.