Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Orúkọ náà Ṣiloh túmọ̀ sí “Ti Ẹni Tí Ó Jẹ́; Ẹni náà Tí Ó Jẹ́ Tirẹ̀.” Nígbà tí ó yá, ó dájú pé Jesu Kristi ni “Ṣiloh” náà, “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Judah.” (Ìṣípayá 5:5) Díẹ̀ lára àwọn Targum wulẹ̀ fi ọ̀rọ̀ náà “Messia” tàbí “ọba Messia” rọ́pò “Ṣiloh.”