Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn ipò tí ọmọ kan ti nílò ìdáàbòbò lọ́wọ́ òbí tí ń lò ó nílòkulò kọ́ ni a ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Bákan náà, bí òbí kejì bá ń sapá láti mú kí ọlá àṣẹ rẹ yìnrìn, bóyá pẹ̀lú èrò láti mú kí àwọn ọmọ fi ọ́ sílẹ̀, ó dára kí o bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ó nírìírí, bí àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristian, sọ̀rọ̀ fún ìmọ̀ràn lórí bí o ṣe lè kojú ipò náà.