Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
d Ní ìyàtọ̀ sí èyí, àkọsílẹ̀ onímìísí ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó dárúkọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ nínú Hébérù orí ìkọkànlá, dà bí pé ó dọ́gbọ́n tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sínú Dáníẹ́lì. (Dáníẹ́lì 6:16-24; Hébérù 11:32, 33) Àmọ́ ṣá, àkọsílẹ̀ orúkọ ti àpọ́sítélì náà kò kún rẹ́rẹ́ bákan náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, títí kan Aísáyà, Jeremáyà àti Ìsíkíẹ́lì, ni a kò dárúkọ nínú àkọsílẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n ó ṣòro kí èyí tó jẹ́ ẹ̀rí pé ṣe ni wọn kò wà rí rárá.