Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe Lẹ́bánónì àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ eléso tó ní àwọn igbó tútù yọ̀yọ̀, tó sì ní àwọn igi kédárì ńláńlá, tó ṣeé fi wé Ọgbà Édẹ́nì. (Sáàmù 29:5; 72:16; Ìsíkíẹ́lì 28:11-13) Àwọn èèyàn mọ Ṣárónì gẹ́gẹ́ bí ibi tó ní àwọn odò àti igi óákù; òkìkí Kámẹ́lì sì kàn fún níní tó ní àwọn ọgbà àjàrà, ọgbà eléso, àti àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè tí àwọn òdòdó bò lọ súà.