Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
d Ọ̀rọ̀ tó dà bí èyí náà ni Jòhánù fi ṣàpèjúwe “Jerúsálẹ́mù tuntun,” ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì bí wọ́n ṣe wà nínú ògo wọn ti ọ̀run. (Ìṣípayá 3:12; 21:10, 22-26) Èyí bá a mu, nítorí pé “Jerúsálẹ́mù tuntun” dúró fún àpapọ̀ àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run lẹ́yìn tí wọ́n ti gba èrè wọn ní ọ̀run, tí àwọn àti Jésù Kristi sì pa pọ̀ di apá pàtàkì lára “obìnrin” Ọlọ́run, ìyẹn “Jerúsálẹ́mù ti òkè.”—Gálátíà 4:26.