Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Nígbà tí Jerome, tó jẹ́ atúmọ̀ Bíbélì (ẹni tí wọ́n bí ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa), ń ṣàlàyé nípa ẹsẹ yìí, ó sọ nípa ohun kan táwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe látijọ́ ní ìparí oṣù tó kẹ́yìn nínú ọdún wọn. Ó kọ̀wé pé: “Wọ́n máa ń tẹ́ tábìlì tó kún fún onírúurú oúnjẹ àti ife ọtí tí wọ́n fi wáìnì dídùn lú, nítorí kí wọ́n lè ṣoríire nídìí ìbísí ti ọdún tó parí, tàbí kí ìbísí lè wà lọ́dún tuntun.”