Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Àwọn gbólóhùn míì nínú Ìwé Mímọ́ fara jọ èyí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀” àti pé “Ọlọ́run . . . jẹ́ iná tó ń jóni run.” (1 Jòhánù 1:5; Hébérù 12:29) Àmọ́, ó ṣe kedere pé ńṣe ni Bíbélì kàn ń fi Jèhófà wé àwọn nǹkan yẹn. Jèhófà dà bí ìmọ́lẹ̀, torí pé ó jẹ́ mímọ́ àti adúróṣinṣin. Kò sí “òkùnkùn,” ìyẹn àìmọ́, nínú rẹ̀ rárá. A sì tún lè fi Jèhófà wé iná torí bó ṣe ń lo agbára rẹ̀ láti fi pa nǹkan run.