Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣòfin pé, ó kéré tán èèyàn gbọ́dọ̀ jìnnà sí adẹ́tẹ̀ tó ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin (nǹkan bíi mítà méjì). Àmọ́ tí afẹ́fẹ́ bá ń fẹ́, adẹ́tẹ̀ náà gbọ́dọ̀ jìnnà tó, ó kéré tán, ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (nǹkan bíi mítà márùndínláàádọ́ta) síbi téèyàn bá wà. Ìwé Midrash Rabbah sọ̀rọ̀ nípa rábì kan tó ń fara pa mọ́ fáwọn adẹ́tẹ̀ àti rábì míì tó ń sọ àwọn adẹ́tẹ̀ lókùúta, láti fi lé wọn dà nù. Torí náà, kì í ṣe ohun tuntun sáwọn adẹ́tẹ̀ táwọn èèyàn bá kórìíra wọn, tí wọ́n sì ń fojú àbùkù wò wọ́n.