Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
d Ńṣe ni ìparun Bábílónì wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti nímùúṣẹ. Lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tó ti nímùúṣẹ ni ìparun ìlú Tírè àti Nínéfè. (Ìsíkíẹ́lì 26:1-5; Sefanáyà 2:13-15) Wòlíì Dáníẹ́lì náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn agbára ayé tó máa ṣàkóso tẹ̀ lé Bábílónì. Lára àwọn agbára ayé náà ni Páṣíà àti Gíríìsì. (Dáníẹ́lì 8:5-7, 20-22) Fún àlàyé lórí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó ṣẹ sára Jésù Kristi, wo Àfikún, ojú ìwé 199 sí 201.