Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Ìdí tá a fi ń pe Jèhófà ní Bàbá ni pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa tó dá wa. (Aísáyà 64:8) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá Jésù, Ọmọ Ọlọ́run là ń pè é. Ìdí yẹn náà ni Bíbélì fi pe àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó kù ní ọmọ Ọlọ́run. Kódà, Bíbélì pe Ádámù tó jẹ èèyàn ní ọmọ Ọlọ́run.—Jóòbù 1:6; Lúùkù 3:38.