Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Bíbélì fi hàn pé wíwulẹ̀ ní ẹ̀rí ọkàn tí kò dani láàmú ò tó. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èmi kò ní ìmọ̀lára ohunkóhun lòdì sí ara mi. Síbẹ̀, nípa èyí, a kò fi mí hàn ní olódodo, ṣùgbọ́n ẹni tí ń wádìí mi wò ni Jèhófà.” (1 Kọ́ríńtì 4:4) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹ̀rí ọkàn àwọn tó ń ṣenúnibíni sáwa Kristẹni lè ṣàì dá wọn lẹ́bi torí wọ́n lè ronú pé ohun tínú Ọlọ́run dùn sí làwọn ń ṣe. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lójú Ọlọ́run, kó má sì da àwa fúnra wa láàmú.—Ìṣe 23:1; 2 Tímótì 1:3.