Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nígbà tí ìwé ìròyìn Scientific American máa sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé “ọkàn ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀,” ó sọ pé: “Tá a bá yọwọ́ ọ̀rọ̀ àfiwé tí Ọlọ́run lò níhìn-ín, kò sírọ́ nínú ohun tó sọ, torí pé gbogbo onírúurú sẹ́ẹ̀lì ló gbọ́dọ̀ wà nínú ẹ̀jẹ̀ kéèyàn tó lè wà láàyè.”