Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Bá a ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ìwà àìmọ́” nínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó ní ìtumọ̀ tó gbòòrò, ó sì lè ní ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀ nínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kì í ṣe gbogbo ìwà àìmọ́ ló máa yọrí sí ìgbẹ́jọ́, bí ẹnikẹ́ni nínú ìjọ bá ń hùwà àìmọ́ tó burú jáì, tó sì kọ̀ láti ronú pìwà dà, ó lè yọrí sí ìyọlẹ́gbẹ́.—2 Kọ́ríńtì 12:21; Éfésù 4:19; wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2006.