Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
d Nínú Májẹ̀mú òfin, obìnrin tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ gbọ́dọ̀ rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (Léfítíkù 12:1-8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òfin yìí ló jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní èrò tó tọ́ nípa ọmọ bíbí, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyẹn ni ò jẹ́ kí wọ́n gba àṣà ìbọ̀rìṣà ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, torí ńṣe lòfin yẹn ń dọ́gbọ́n rán wọn létí pé téèyàn bá bímọ ogún tó ń fún ọmọ náà ni ẹ̀ṣẹ̀.—Sáàmù 51:5.