Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn orúkọ tó ṣàpèjúwe irú ẹni tí Sátánì jẹ́ (Alátakò, Abanijẹ́, Atannijẹ, Adánniwò, Òpùrọ́) kò fi hàn pé ó lágbára láti ṣàwárí ohun tó wà nínú ọkàn àti àyà wa. Àmọ́, ti Jèhófà yàtọ̀, torí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà,” ó sì pe Jésù ní ẹni tó “ń wá inú kíndìnrín àti ọkàn-àyà.”—Òwe 17:3; Ìṣípayá 2:23.