Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìwé Mímọ́ sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14 pé: “Odò kan wà tí ń ṣàn jáde láti Édẹ́nì láti bomi rin ọgbà náà, ibẹ̀ ni ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí pínyà, ó sì di ohun tí a lè pè ní ẹ̀ka mẹ́rin. Orúkọ èyí èkíní ni Píṣónì . . . Orúkọ odò kejì sì ni Gíhónì . . . Orúkọ odò kẹta sì ni Hídẹ́kẹ́lì [tàbí Tígírísì]; òun ni èyí tí ó lọ sí ìlà-oòrùn Ásíríà. Odò kẹrin sì ni Yúfírétì.” Ní òde òní kò sí èèyàn tó mọ odó tó ń jẹ́ Píṣónì àti èyí tó ń jẹ́ Gíhónì, kò sì sí ẹni tó mọ ojú ibi tí odò méjèèjì yìí wà.