Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni yàtọ̀ sí ìgbà tí ara ẹni bá dìde, bí ẹni tí ara ẹ̀ wà lọ́nà láti ní ìbálòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọmọkùnrin kan lè jí lójú oorun kó wá rí i pé ẹ̀yà ìbímọ òun dìde tàbí pé àtọ̀ ti jáde lára òun nígbà tóun ṣì ń sùn. Bákan náà, àwọn ọmọbìnrin míì kàn lè rí i pé ara àwọn wà lọ́nà láti ní ìbálòpọ̀ láìjẹ́ pé àwọn ni wọ́n fà á, pàápàá tó bá kù díẹ̀ kí wọ́n ṣe nǹkan oṣù tàbí gbàrà tí wọ́n ṣe é tán. Fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni yàtọ̀ pátápátá sí èyí, ṣe ni ẹni tó ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ kí ara rẹ̀ lè dìde bí ẹni tó fẹ́ ní ìbálòpọ̀.