Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Àwọn tó ń ṣèwádìí ti fojú bù ú pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn tó ń gbé ní ìlú Samáríà, tó jẹ́ olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, nígbà ayé Jónà tó ọ̀kẹ́ kan [20,000] sí ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000]. Ìyẹn ò tó ìdámẹ́rin àwọn tó ń gbé ní ìlú Nínéfè. Nígbà tí ìlú Nínéfè ṣì wà lójú ọpọ́n, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ni ìlú tó tóbi jù lọ láyé.